Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 31:22-30 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Mose bá kọ orin yìí ní ọjọ́ náà-gan an, ó sì kọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

23. OLUWA fi iṣẹ́ lé Joṣua ọmọ Nuni lọ́wọ́, ó ní, “Múra gírí kí o sì mú ọkàn gidigidi, nítorí ìwọ ni o óo kó àwọn ọmọ Israẹli wọ ilẹ̀ tí mo ti búra láti fún wọn. N óo wà pẹlu rẹ.”

24. Nígbà tí Mose kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé òfin yìí tán patapata,

25. ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n ru àpótí majẹmu OLUWA,

26. ó ní, “Ẹ fi ìwé òfin yìí sí ẹ̀gbẹ́ àpótí majẹmu OLUWA Ọlọrun yín, kí ó wà níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pẹlu yín;

27. nítorí mo mọ̀ pé ọlọ̀tẹ̀ ati olóríkunkun ni yín; nígbà tí mo wà láàyè pẹlu yín lónìí, ẹ̀ ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA, kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ìgbà tí mo bá kú tán.

28. Ẹ pe gbogbo àwọn àgbààgbà ẹ̀yà yín wá sọ́dọ̀ mi, ati gbogbo àwọn olórí ninu yín, kí àwọn náà lè máa gbọ́ bí mo ti ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, kí ẹ sì pe ọ̀run ati ayé láti ṣe ẹlẹ́rìí wọn.

29. Nítorí mo mọ̀ dájú pé gẹ́rẹ́ tí mo bá kú tán, ìṣekúṣe ni ẹ óo máa ṣe, ẹ óo sì yipada kúrò ní ọ̀nà tí mo ti pa láṣẹ fun yín, ibi ni yóo sì ba yín ní ọjọ́ iwájú, nítorí pé ẹ óo ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA. Iṣẹ́ ọwọ́ yín yóo sì mú un bínú.”

30. Mose ka gbogbo ọ̀rọ̀ orin náà patapata sí etígbọ̀ọ́ àpéjọ àwọn ọmọ Israẹli.

Ka pipe ipin Diutaronomi 31