Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 29:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. A gba ilẹ̀ wọn, a sì fi fún ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn.

9. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ máa tẹ̀lé majẹmu yìí, kí ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé lè máa yọrí sí rere.

10. “Gbogbo yín pátá ni ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ati gbogbo àwọn olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olóyè ati àwọn ọkunrin Israẹli.

11. Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àwọn aya yín, ati àwọn àlejò tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ yín; àwọn tí wọn ń wá igi fun yín, ati àwọn tí wọn ń pọnmi fun yín.

12. Kí gbogbo yín lè bá OLUWA Ọlọrun yín dá majẹmu lónìí,

13. kí ó lè fi ìdí yín múlẹ̀ bí eniyan rẹ̀, kí ó sì máa jẹ́ Ọlọrun yín; gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, ati bí ó ti búra fún Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu àwọn baba ńlá yín.

14. ‘Kìí ṣe ẹ̀yin nìkan ni mò ń bá dá majẹmu yìí, tí mo sì ń búra fún,

15. ṣugbọn ati àwọn tí wọn kò sí níhìn-ín lónìí, ati ẹ̀yin alára tí ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ni majẹmu náà wà fún.’

16. “Ẹ̀yin náà mọ̀ bí ayé wa ti rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati bí a ti la ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a gbà kọjá.

17. Ẹ sì ti rí àwọn ohun ìríra wọn: àwọn oriṣa wọn tí wọ́n fi igi gbẹ́, èyí tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, èyí tí wọ́n fi fadaka ṣe, ati èyí tí wọ́n fi wúrà ṣe.

18. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí á má ṣe rí ẹnikẹ́ni ninu yín, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, tabi ìdílé kan, tabi ẹ̀yà kan, tí ọkàn rẹ̀ yóo yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín lónìí, tí yóo sì lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń bọ. Nítorí pé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo dàbí igi tí ń so èso tí ó korò, tí ó sì ní májèlé ninu.

19. Kí irú ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu má baà dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pé ‘Kò séwu, bí mo bá fẹ́ mo lè ṣe orí kunkun kí n sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ ara mi.’ Èyí yóo kó ìparun bá gbogbo yín, ati àwọn tí wọn ń ṣe ibi ati àwọn tí wọn ń ṣe rere.

Ka pipe ipin Diutaronomi 29