Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 29:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA pàṣẹ fún Mose pé kí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu mìíràn ní ilẹ̀ Moabu, yàtọ̀ sí èyí tí ó ti bá wọn dá ní òkè Horebu.

2. Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti rí gbogbo ohun tí OLUWA ṣe sí Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti.

3. Ẹ fi ojú yín rí àwọn ìdààmú ńláńlá tí ó bá wọn, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe.

4. Ṣugbọn títí di òní yìí, OLUWA kò tíì jẹ́ kí òye ye yín, ojú yín kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni etí yín kò gbọ́ràn.

5. Odidi ogoji ọdún ni mo fi ko yín la ààrin aṣálẹ̀ kọjá. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni bàtà kò gbó mọ yín lẹ́sẹ̀.

6. Ẹ kò jẹ oúnjẹ gidi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA ni OLUWA Ọlọrun yín.

7. Nígbà tí ẹ dé ibí yìí, Sihoni, ọba Heṣiboni ati Ogu, ọba Baṣani gbógun tì wá, ṣugbọn a ṣẹgun wọn.

8. A gba ilẹ̀ wọn, a sì fi fún ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn.

9. Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ máa tẹ̀lé majẹmu yìí, kí ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé lè máa yọrí sí rere.

10. “Gbogbo yín pátá ni ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ati gbogbo àwọn olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olóyè ati àwọn ọkunrin Israẹli.

Ka pipe ipin Diutaronomi 29