Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 27:14-26 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Àwọn ọmọ Lefi yóo wí ketekete fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé:

15. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yá ère gbígbẹ́ tabi ère tí wọ́n fi irin rọ. Ohun ìríra ni lójú OLUWA, pé kí àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà fi ọwọ́ gbẹ́ nǹkan, kí ẹnìkan wá gbé e kalẹ̀ níkọ̀kọ̀, kí ó máa bọ ọ́.’“Gbogbo àwọn eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

16. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá tàbùkù baba tabi ìyá rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

17. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yẹ ààlà ilẹ̀ ẹnìkejì rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

18. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣi afọ́jú lọ́nà.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

19. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹni tí ó bá yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò po, tabi ti aláìní baba, tabi ti opó.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

20. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé ó dójúti baba rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

21. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀.’“Gbogbo eniyan yóo dáhùn pé, ‘Amin.’

22. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ tabi ọmọ baba rẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

23. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ìyá aya rẹ̀ lòpọ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

24. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá pa aládùúgbò rẹ̀ níkọ̀kọ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

25. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa aláìṣẹ̀.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

26. “ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí kò bá pa gbogbo àwọn òfin yìí mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn.’“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

Ka pipe ipin Diutaronomi 27