Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 24:8-17 BIBELI MIMỌ (BM)

8. “Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá mú yín, ẹ ṣọ́ra gidigidi, kí ẹ sì rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá là sílẹ̀ fun yín láti ṣe, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún wọn.

9. Ẹ ranti ohun tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe sí Miriamu nígbà tí ẹ̀ ń jáde ti ilẹ̀ Ijipti bọ̀.

10. “Tí ẹ bá yá ẹnìkejì yín ní nǹkankan, ẹ kò gbọdọ̀ wọ ilé rẹ̀ lọ láti wá ohun tí yóo fi dógò.

11. Ìta ni kí ẹ dúró sí, kí ẹ sì jẹ́ kí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú un wá fun yín.

12. Bí ó bá jẹ́ aláìní ni olúwarẹ̀, aṣọ tí ó bá fi dógò kò gbọdọ̀ sùn lọ́dọ̀ yín.

13. Ẹ gbọdọ̀ dá a pada fún un ní alẹ́, kí ó lè rí aṣọ fi bora sùn, kí ó lè súre fun yín. Èyí yóo jẹ́ ìwà òdodo lójú OLUWA Ọlọrun yín.

14. “Ẹ kò gbọdọ̀ rẹ́ alágbàṣe yín tí ó jẹ́ talaka ati aláìní jẹ, kì báà jẹ́ ọmọ Israẹli ẹlẹgbẹ́ yín, tabi àlejò tí ó ń gbé ọ̀kan ninu àwọn ìlú yín.

15. Lojoojumọ, kí oòrùn tó wọ̀, ni kí ẹ máa san owó iṣẹ́ òòjọ́ rẹ̀ fún un, nítorí pé ó nílò owó yìí, kò sì sí ohun mìíràn tí ó gbẹ́kẹ̀lé. Bí ẹ kò bá san án fún un, yóo ké pe OLUWA, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn.

16. “Ẹ kò gbọdọ̀ pa baba dípò ọmọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ kò gbọdọ̀ pa ọmọ dípò baba, olukuluku ni yóo kú fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó bá dá.

17. “Ẹ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò tabi aláìníbaba po, bẹ́ẹ̀ sì ni, tí ẹ bá yá opó ní ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba aṣọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.

Ka pipe ipin Diutaronomi 24