Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 23:15-25 BIBELI MIMỌ (BM)

15. “Bí ẹrú kan bá sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, tí ó bá tọ̀ yín wá, ẹ kò gbọdọ̀ lé e pada sọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀.

16. Ẹ jẹ́ kí ó máa bá yín gbé, kí ó wà láàrin yín ninu èyíkéyìí tí ó bá yàn ninu àwọn ìlú yín. Ibi tí ó bá wù ú ni ó lè gbé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ni ín lára.

17. “Ẹnikẹ́ni ninu àwọn eniyan Israẹli, kì báà jẹ́ ọkunrin tabi obinrin, kò gbọdọ̀ sọ ara rẹ̀ di alágbèrè ní ilé oriṣa kankan.

18. Ọkunrin tabi obinrin kankan kò gbọdọ̀ mú owó tí ó bá gbà ní ibi àgbèrè ṣíṣe wá sinu ilé OLUWA láti san ẹ̀jẹ́kẹ́jẹ̀ẹ́ tí ó bá jẹ́, nítorí pé, àgbèrè ṣíṣe jẹ́ ohun ìríra níwájú OLUWA Ọlọrun yín.

19. “Tí ẹ̀yin ọmọ Israẹli bá yá ara yín lówó, tabi oúnjẹ tabi ohunkohun, ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé lórí rẹ̀.

20. Bí ẹ bá yá àlejò ní nǹkan, ẹ lè gba èlé, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ yá arakunrin yín ní ohunkohun kí ẹ sì gba èlé, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun yín ninu ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ láti gbà.

21. “Nígbà tí ẹ bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ kò gbọdọ̀ má san ẹ̀jẹ́ náà, nítorí OLUWA Ọlọrun yín yóo bèèrè rẹ̀ lọ́wọ́ yín, yóo sì di ẹ̀ṣẹ̀ sí yín lọ́rùn bí ẹ kò bá san án.

22. Ṣugbọn tí ẹ kò bá jẹ́jẹ̀ẹ́ rárá, kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ fun yín.

23. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá ti fínnúfẹ́dọ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ ohunkohun fún OLUWA Ọlọrun yín, ẹ ti fi ẹnu yín ṣèlérí, ẹ sì níláti rí i pé, ẹ mú ẹ̀jẹ́ náà ṣẹ.

24. “Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní ibi ọgbà àjàrà ẹlòmíràn, ẹ lè jẹ ìwọ̀nba èso àjàrà tí ó bá tẹ́ yín lọ́rùn, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ mú ẹyọkan lọ́wọ́ lọ.

25. Nígbà tí ẹ bá ń kọjá lọ ní oko ọkà ẹlòmíràn, tí wọn kò tíì kórè, ẹ lè fi ọwọ́ ya ìwọ̀nba tí ẹ lè jẹ, ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ fi dòjé gé ọkà ọlọ́kà.

Ka pipe ipin Diutaronomi 23