Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 2:13-21 BIBELI MIMỌ (BM)

13. “Ẹ dìde nisinsinyii kí ẹ sì kọjá sí òdìkejì odò Seredi. A sì ṣí lọ sí òdìkejì odò Seredi.

14. Lẹ́yìn ọdún mejidinlogoji gbáko tí a ti kúrò ní Kadeṣi Banea, ni a tó kọjá odò Seredi, títí tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun ún jà ninu ìran náà fi run tán patapata, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti búra pé yóo rí.

15. OLUWA dójúlé wọn nítòótọ́ títí gbogbo wọn fi parun patapata ninu ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.

16. “Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n tó ogun-ún jà ti kú tán láàrin àwọn ọmọ Israẹli,

17. OLUWA bá wí fún mi pé,

18. ‘Òní ni ọjọ́ tí ẹ óo ré ààlà àwọn ará Moabu kọjá ní Ari.

19. Nígbà tí ẹ bá súnmọ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Amoni, ẹ má ṣe dà wọ́n láàmú, ẹ má sì bá wọn jagun, nítorí pé n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ìní, nítorí pé, àwọn ọmọ Lọti ni mo ti fún.’ ”

20. (Ibẹ̀ ni wọ́n ń pè ní ilẹ̀ Refaimu, nítorí pé, àwọn Refaimu ni wọ́n ti ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀, ṣugbọn àwọn ará Amoni a máa pè wọ́n ní Samsumimu.

21. Àwọn tí à ń pè ní Refaimu yìí pọ̀, wọ́n lágbára, wọ́n sì ṣígbọnlẹ̀ bí àwọn ọmọ Anaki, àwọn òmìrán. Ṣugbọn OLUWA pa wọ́n run fún àwọn ará Amoni, wọ́n gba ilẹ̀ wọn, wọ́n sì tẹ̀dó sibẹ.

Ka pipe ipin Diutaronomi 2