Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 2:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Nígbà tí ó yá, a pada sinu aṣálẹ̀ ní ọ̀nà Òkun Pupa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi; a sì rìn káàkiri lórí òkè Seiri fún ọpọlọpọ ọjọ́.

2. “OLUWA bá wí fún mi pé,

3. ‘Ìrìn tí ẹ rìn káàkiri ní agbègbè olókè yìí tó gẹ́ẹ́; ẹ yipada sí apá àríwá.’

4. OLUWA ní kí n pàṣẹ pé, ‘Ilẹ̀ tí ẹ óo là kọjá yìí jẹ́ ilẹ̀ àwọn ọmọ Esau, àwọn arakunrin yín, tí wọn ń gbé òkè Seiri. Ẹ̀rù yín yóo máa bà wọ́n, nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi;

5. ẹ má bá wọn jà, nítorí n kò ní fun yín ní ilẹ̀ wọn, bí ó ti wù kí ó kéré tó. Mo ti fi gbogbo ilẹ̀ Edomu ní òkè Seiri fún arọmọdọmọ Esau, gẹ́gẹ́ bí ìní wọn.

6. Ẹ óo ra oúnjẹ jẹ lọ́wọ́ wọn, ẹ óo sì ra omi mu lọ́wọ́ wọn.’

7. “Ẹ ranti bí OLUWA Ọlọrun yín ti bukun yín ninu gbogbo ohun tí ẹ dáwọ́lé, ó sì ti tọ́jú yín ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀ ń rìn kiri ninu aṣálẹ̀ ńláńlá yìí. Ó ti wà pẹlu yín láti ogoji ọdún sẹ́yìn wá, ohunkohun kò sì jẹ yín níyà.

8. “A bá kọjá lọ láàrin àwọn arakunrin wa, àwọn ọmọ Esau tí wọn ń gbé òkè Seiri, a ya ọ̀nà tí ó lọ láti Elati ati Esiongeberi sí Araba sílẹ̀. A yipada a sì gba ọ̀nà aṣálẹ̀ Moabu.

Ka pipe ipin Diutaronomi 2