Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 18:13-22 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Gbogbo ìwà ati ìṣe yín níláti jẹ́ èyí tí ó tọ́ níwájú OLUWA Ọlọrun yín.

14. “Àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ óo gba ilẹ̀ wọn yìí a máa ṣe àyẹ̀wò, wọn a sì máa gbọ́ ti àwọn aláfọ̀ṣẹ, ṣugbọn ní tiyín, OLUWA Ọlọrun yín kò gbà fun yín pé kí ẹ ṣe bẹ́ẹ̀.

15. OLUWA Ọlọrun yín yóo gbé wolii kan dìde tí yóo dàbí mi láàrin yín, tí yóo jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín, òun ni kí ẹ máa gbọ́ràn sí lẹ́nu.

16. “Bíi ti ọjọ́ tí ẹ péjọ ní òkè Horebu tí ẹ bẹ OLUWA Ọlọrun yín, tí ẹ sọ fún mi pé, ‘Má jẹ́ kí á gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun wa mọ́, tabi kí á rí iná ńlá yìí mọ́; kí á má baà kú.’

17. OLUWA wí fún mi nígbà náà pé, ‘Gbogbo ohun tí wọ́n sọ patapata ni ó dára.

18. N óo gbé wolii kan dìde gẹ́gẹ́ bíì rẹ, láàrin àwọn arakunrin wọn, n óo fi ọ̀rọ̀ mi sí i lẹ́nu, yóo sì máa sọ ohun gbogbo tí mo bá pa láṣẹ fún wọn.

19. Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ mi, tí yóo máa sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra mi ni n óo jẹ olúwarẹ̀ níyà.

20. Ṣugbọn wolii tí ó bá fi orúkọ mi jẹ́ iṣẹ́ tí n kò rán an, tabi tí ó jẹ́ iṣẹ́ kan fun yín ní orúkọ àwọn oriṣa, wolii náà gbọdọ̀ kú ni.’

21. “Bí ẹ bá ń rò ninu ọkàn yín pé, báwo ni ẹ óo ti ṣe mọ ìgbà tí wolii kan bá ń jẹ́ iṣẹ́ tí Ọlọrun kò rán an.

22. Nígbà tí wolii kan bá jíṣẹ́ ní orúkọ OLUWA, bí ohun tí ó sọ pé yóo ṣẹlẹ̀ kò bá ṣẹlẹ̀, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ni ó rán an; wolii náà ń dá iṣẹ́ ara rẹ̀ jẹ́ ni, ẹ má bẹ̀rù rẹ̀.

Ka pipe ipin Diutaronomi 18