Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 16:3-12 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ burẹdi tí ó ní ìwúkàrà ninu pẹlu ẹbọ náà; ọjọ́ meje ni ẹ óo fi jẹ ẹ́ pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà. Oúnjẹ náà jẹ́ oúnjẹ ìpọ́njú, nítorí pé ìkánjú ni ẹ fi jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti; ẹ óo sì lè máa ranti ọjọ́ náà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Ijipti ní gbogbo ọjọ́ ayé yín.

4. Wọn kò gbọdọ̀ bá ìwúkàrà lọ́wọ́ yín, ati ní gbogbo agbègbè yín, fún ọjọ́ meje. Ẹran tí ẹ bá fi rúbọ kò gbọdọ̀ ṣẹ́kù ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kinni, títí di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.

5. “Ẹ kò gbọdọ̀ rú ẹbọ àjọ ìrékọjá láàrin èyíkéyìí ninu àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fi fun yín.

6. Àfi ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, níbẹ̀ ni ẹ ti gbọdọ̀ máa rú ẹbọ àjọ ìrékọjá ní ìrọ̀lẹ́, nígbà tí oòrùn ń lọ wọ̀ ní àkókò tí ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

7. Bíbọ̀ ni kí ẹ bọ̀ ọ́, kí ẹ jẹ ẹ́ ní ibi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn pé kí ẹ ti máa jọ́sìn, nígbà tí ó bá sì di òwúrọ̀ ẹ óo pada lọ sinu àgọ́ yín.

8. Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi jẹ burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, ní ọjọ́ keje, ẹ óo pe àpèjọ tí ó ní ọ̀wọ̀, ẹ óo sì sin OLUWA Ọlọrun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà.

9. “Ẹ óo ka ọ̀sẹ̀ meje, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ tí ẹ kọ́kọ́ ti dòjé bọ inú oko ọkà, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí gé e.

10. Nígbà náà, ẹ óo ṣe àsè àjọ ọ̀sẹ̀, tíí ṣe àjọ̀dún ìkórè fún OLUWA Ọlọrun yín; pẹlu ọrẹ àtinúwá. Ẹ óo mú ọrẹ náà wá bí OLUWA Ọlọrun yín bá ti bukun yín.

11. Ẹ óo máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, níbikíbi tí ó bá yàn pé kí ẹ ti máa sin òun, ẹ̀yin, àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹbinrin ati iranṣẹkunrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọn ń gbé àwọn ìlú yín; àwọn àlejò, àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó, tí wọ́n wà láàrin yín.

12. Ẹ ranti pé ẹ ti jẹ́ ẹrú rí ní ilẹ̀ Ijipti. Ẹ ṣọ́ra kí ẹ lè máa tẹ̀lé àwọn ìlànà wọnyi.

Ka pipe ipin Diutaronomi 16