Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 15:18-23 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Má jẹ́ kí ó ni ọ́ lára láti dá a sílẹ̀ kí ó sì máa lọ lọ́fẹ̀ẹ́, nítorí pé, ìdajì owó ọ̀yà alágbàṣe ni ó ti fi ń sìn ọ́, fún odidi ọdún mẹfa. Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ ṣe, kí OLUWA Ọlọrun yín lè bukun ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe.

19. “Gbogbo àkọ́bí tí ẹran ọ̀sìn bá bí ninu agbo ẹran yín, tí ó bá jẹ́ akọ ni ẹ gbọdọ̀ yà á sọ́tọ̀ fún OLUWA Ọlọrun. Ẹ kò gbọdọ̀ fi akọ tí ó jẹ́ àkọ́bí ninu agbo mààlúù yín ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì gbọdọ̀ rẹ́ irun àgbò tí ó jẹ́ àkọ́bí aguntan yín.

20. Níbikíbi tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn, ni ẹ ti gbọdọ̀ máa jẹ wọ́n níwájú rẹ̀, ní ọdọọdún; ẹ̀yin ati gbogbo ilé yín.

21. Ṣugbọn bí ó bá ní àbààwọ́n kan, bóyá ó jẹ́ arọ ni, tabi afọ́jú, tabi ó ní àbààwọ́n kankan, ẹ kò gbọdọ̀ fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín,

22. jíjẹ ni kí ẹ jẹ ẹ́ ní ààrin ìlú yín, ati àwọn tí wọ́n mọ́, ati àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ ni wọ́n lè jẹ ninu rẹ̀, bí ìgbà tí eniyan jẹ ẹran èsúó tabi àgbọ̀nrín ni.

23. Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nìkan ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ; dídà ni kí ẹ dà á sílẹ̀ bí omi.

Ka pipe ipin Diutaronomi 15