Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 14:6-20 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Àwọn ẹranko tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji, tabi tí wọ́n bá ní ìka ẹsẹ̀, tí wọ́n sì ń jẹ àpọ̀jẹ, irú wọn ni kí ẹ máa jẹ.

7. Ṣugbọn ninu àwọn ẹran tí wọn ń jẹ àpọ̀jẹ ati àwọn tí pátákò ẹsẹ̀ wọn là sí meji tabi tí wọ́n ní ìka ẹsẹ̀, àwọn wọnyi ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ: ràkúnmí, ati ehoro ati ẹranko kan tí ó dàbí gara. Àwọn wọnyi ń jẹ àpọ̀jẹ lóòótọ́, ṣugbọn pátákò ẹsẹ̀ wọn kò là, nítorí náà, wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín.

8. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹlẹ́dẹ̀, lóòótọ́ ó ní ìka ẹsẹ̀, ṣugbọn kì í jẹ àpọ̀jẹ, nítorí náà, ó jẹ́ aláìmọ́ fun yín. Ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹran ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fara kan òkú wọn.

9. “Ninu gbogbo àwọn abẹ̀mí tí ó wà ninu omi, àwọn wọnyi ni kí ẹ máa jẹ: gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́ ni ẹ lè jẹ.

10. Ṣugbọn èyíkéyìí tí kò bá ní lẹbẹ ati ìpẹ́, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n, nítorí wọ́n jẹ́ aláìmọ́ fun yín.

11. “Ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ẹyẹ tí wọ́n bá mọ́.

12. Ṣugbọn ẹ kò gbọdọ̀ jẹ àwọn ẹyẹ wọnyi: ẹyẹ idì, igún ati idì tí ń jẹ ẹja,

13. ati àṣá gidi, ati oríṣìíríṣìí àṣá mìíràn, ati igún gidi, ati àwọn oríṣìíríṣìí igún yòókù,

14. ati oríṣìíríṣìí àwọn ẹyẹ ìwò,

15. ati ògòǹgò, ati òwìwí, ati ẹ̀lulùú, ati oríṣìíríṣìí àwòdì,

16. ati òwìwí ńlá, ati òwìwí kéékèèké, ati ògbúgbú,

17. ati ẹyẹ òfù, ati àkàlà, ati ẹyẹ ìgo,

18. ati ẹyẹ àkọ̀, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ òòdẹ̀, ati ẹyẹ atọ́ka, ati àdán.

19. “Gbogbo àwọn kòkòrò tí wọn ń fò jẹ́ aláìmọ́ fun yín, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ wọ́n.

20. Ṣugbọn ẹ lè jẹ gbogbo àwọn ohun tí ó bá ní ìyẹ́, tí wọ́n sì mọ́.

Ka pipe ipin Diutaronomi 14