Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 11:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Nítorí náà, ẹ fẹ́ràn OLUWA Ọlọrun yín, kí ẹ sì máa tẹ̀lé gbogbo ìkìlọ̀ ati ìlànà, ati ìdájọ́, ati òfin rẹ̀ nígbà gbogbo.

2. (Kì í ṣe àwọn ọmọ yín tí kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí mò ń sọ ni mò ń bá sọ̀rọ̀); nítorí náà, ẹ máa ṣe akiyesi ìtọ́ni OLUWA Ọlọrun yín, ati títóbi rẹ̀, ati agbára rẹ̀, ati ipá rẹ̀.

3. Ẹ ranti gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe ní ilẹ̀ Ijipti sí ọba Farao, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

4. Ẹ ranti ohun tí ó ṣe sí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Ijipti ati sí àwọn ẹṣin wọn ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn; bí ó ti jẹ́ kí omi Òkun Pupa bò wọ́n mọ́lẹ̀ nígbà tí wọ́n ń le yín bọ̀, ati bí OLUWA ti pa wọ́n run títí di òní olónìí.

Ka pipe ipin Diutaronomi 11