Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 10:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “OLUWA sọ fún mi pé, ‘Gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, fi igi kan àpótí kan kí o sì gun orí òkè tọ̀ mí wá.

2. N óo kọ ohun tí mo kọ sí ara àwọn tabili ti àkọ́kọ́ tí o fọ́ sí ara wọn, o óo sì kó wọn sinu àpótí náà.’

3. “Mo bá fi igi akasia kan àpótí kan, mo sì gbẹ́ tabili òkúta meji bíi ti àkọ́kọ́, mo gun orí òkè lọ pẹlu àwọn tabili náà lọ́wọ́ mi.

4. OLUWA bá kọ àwọn òfin mẹ́wàá tí ó kọ sí ara àwọn tabili àkọ́kọ́ sára àwọn tabili náà, ó sì kó wọn fún mi. Àwọn òfin mẹ́wàá yìí ni OLUWA sọ fun yín lórí òkè láti ààrin iná ní ọjọ́ tí ẹ péjọ sí ẹsẹ̀ òkè náà.

5. Mo gbéra, mo sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, mo sì kó àwọn tabili náà sinu àpótí tí mo kàn, wọ́n sì wà níbẹ̀ bí OLUWA ti pàṣẹ fún mi.”

6. (Àwọn eniyan Israẹli rìn láti Beeroti Benejaakani lọ sí Mosera, ibẹ̀ ni Aaroni kú sí, tí wọ́n sì sin ín sí. Eleasari ọmọ rẹ̀ sì ń ṣe iṣẹ́ alufaa dípò rẹ̀.

7. Wọ́n gbéra láti ibẹ̀, wọ́n lọ sí Gudigoda. Láti Gudigoda, wọ́n lọ sí Jotibata, ilẹ̀ tí ó kún fún ọpọlọpọ odò tí ń ṣàn.

Ka pipe ipin Diutaronomi 10