Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 1:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọ̀rọ̀ tí Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ninu aṣálẹ̀ nìyí, ní òdìkejì odò Jọdani, ní Araba tí ó kọjú sí Sufu, láàrin Parani, Tofeli, Labani, Haserotu ati Disahabu.

2. Ìrìn ọjọ́ mọkanla ni láti Horebu dé Kadeṣi Banea, tí eniyan bá gba ọ̀nà òkè Seiri.

3. Ní ọjọ́ kinni oṣù kọkanla, ní ogoji ọdún tí wọ́n ti kúrò ní Ijipti, ni Mose bá àwọn eniyan Israẹli sọ ohun tí OLUWA pàṣẹ fún un láti sọ fún wọn;

4. lẹ́yìn tí ó ti ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori tí ń gbé Heṣiboni; ati Ogu, ọba àwọn ará Baṣani, tí ń gbé Aṣitarotu ati Edirei.

5. Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn, ní ilẹ̀ Moabu, ni Mose ti ṣe àlàyé àwọn òfin wọnyi. Ó ní,

6. “OLUWA Ọlọrun wa sọ fún wa ní Horebu pé, a ti pẹ́ tó ní ẹsẹ̀ òkè náà.

7. Ó ní kí á dìde, kí á bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí agbègbè olókè ti àwọn ará Amori, ati gbogbo agbègbè tí ó yí wọn ká ní Araba, ní àwọn agbègbè olókè ati ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, ati èyí tí ó wà létí òkun tí wọn ń pè ní Mẹditarenia, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani ati Lẹbanoni, títí dé odò ńlá nnì, àní odò Yufurate.

8. Ó ní, ‘Ẹ wò ó! Mo ti pèsè ilẹ̀ náà fun yín, ẹ lọ, kí ẹ sì gbà á; Èmi OLUWA ti búra láti fún Abrahamu ati Isaaki, ati Jakọbu, àwọn baba ńlá yín ati arọmọdọmọ wọn.’ ”

9. “Mo sọ fun yín nígbà náà pé, èmi nìkan kò ní lè máa ṣe àkóso yín.

Ka pipe ipin Diutaronomi 1