Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 8:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọdún kẹta tí Beṣasari jọba ni èmi Daniẹli rí ìran kan lẹ́yìn ti àkọ́kọ́.

2. Ninu ìran náà, mo rí i pé mo wà ní Susa, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Elamu. Mo rí i pé mo wà létí odò Ulai.

3. Bí mo ti gbé ojú sókè, mo rí i tí àgbò kan dúró létí odò, ó ní ìwo meji tí ó ga sókè, ṣugbọn ọ̀kan gùn ju ekeji lọ. Èyí tí ó gùn jù ni ó hù kẹ́yìn.

4. Mo rí i tí àgbò náà bẹ̀rẹ̀ sí kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, kò sí ẹranko tí ó lè dúró níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti wù ú, ó sì ń gbéraga.

5. Bí mo tí ń ronú nípa rẹ̀, mo rí i tí òbúkọ kan ti ìhà ìwọ̀ oòrùn la gbogbo ayé kọjá wá láìfi ẹsẹ̀ kan ilẹ̀, ó sì ní ìwo ńlá kan láàrin ojú rẹ̀ mejeeji.

6. Ó súnmọ́ àgbò tí ó ní ìwo meji, tí mo kọ́ rí tí ó dúró létí odò, ó sì pa kuuru sí i pẹlu ibinu ńlá.

7. Mo rí i ó súnmọ́ àgbò náà, ó fi tìbínú-tìbínú kàn án, ìwo mejeeji àgbò náà sì ṣẹ́. Àgbò náà kò lágbára láti dúró níwájú rẹ̀. Ó tì í ṣubú, ó sì ń fi ẹsẹ̀ tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀. Kò sì sí ẹni tí ó lè gba àgbò náà lọ́wọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Daniẹli 8