Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 5:1-14 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kan, Beṣasari ọba, se àsè ńlá kan fún ẹgbẹrun (1,000) ninu àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì ń mu ọtí níwájú wọn.

2. Nígbà tí ó tọ́ ọtí náà wò, ó pàṣẹ pé kí wọn kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí Nebukadinesari, baba rẹ̀, kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, kí òun, ati àwọn ìjòyè òun, àwọn ayaba ati àwọn obinrin òun lè máa fi wọ́n mu ọtí.

3. Wọ́n bá kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí wọ́n kó ninu tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí.

4. Bí wọn tí ń mu ọtí, ni wọ́n ń yin ère wúrà, ère fadaka, ère irin, ère igi, ati ère òkúta.

5. Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí ara ògiri ààfin níbi tí iná fìtílà tan ìmọ́lẹ̀ sí, ọba rí ọwọ́ náà, bí ó ti ń kọ̀wé.

6. Ojú ọba yipada, ẹ̀rù bà á, ara rẹ̀ ń gbọ̀n, orúnkún rẹ̀ sì ń lu ara wọn.

7. Ó kígbe sókè pé kí wọ́n tètè lọ pe àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea ati àwọn awòràwọ̀ wá. Nígbà tí wọ́n dé, ọba sọ fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka ohun tí wọ́n kọ sára ògiri yìí, tí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fi aṣọ elése àlùkò dá a lọ́lá, n óo ní kí wọ́n fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, yóo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ninu ìjọba mi.”

8. Gbogbo àwọn amòye ọba wá, wọn kò lè ka àwọn àkọsílẹ̀ náà, wọn kò sì lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.

9. Ọkàn Beṣasari dàrú, ojú rẹ̀ yipada. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dààmú, wọn kò sì mọ ohun tí wọ́n lè ṣe.

10. Nígbà tí ayaba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ó wọ inú gbọ̀ngàn àsè náà, ó sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, kí ọba kí ó pẹ́, má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí dààmú rẹ tabi kí ó mú kí ojú rẹ fàro.

11. Ẹnìkan ń bẹ ní ìjọba rẹ tí ó ní ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ninu. Ní àkókò baba rẹ, a rí ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, ati ọgbọ́n bíi ti Ọlọrun ninu rẹ̀. Òun ni baba rẹ, Nebukadinesari ọba, fi ṣe olórí gbogbo àwọn pidánpidán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn Kalidea ati àwọn awòràwọ̀;

12. nítorí pé Daniẹli, tí ọba sọ ní Beteṣasari, ní ìmọ̀ ati òye láti túmọ̀ àlá, ati láti ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀, ati láti yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú. Ranṣẹ pe Daniẹli yìí, yóo sì sọ ìtumọ̀ fún ọ.”

13. Wọ́n bá mú Daniẹli wá siwaju ọba. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ẹrú, tí baba mi kó wá láti ilẹ̀ Juda?

14. Mo ti gbọ́ pé ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ń bẹ ninu rẹ; ati pé o ní ìmọ̀, òye, ati ọgbọ́n tí kò lẹ́gbẹ́.

Ka pipe ipin Daniẹli 5