Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Daniẹli 11:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Lẹ́yìn ọdún díẹ̀, ọba Ijipti yóo ní àjọṣepọ̀ pẹlu ọba Siria, ní ìhà àríwá, ọmọbinrin ọba Ijipti yóo wá sí ọ̀dọ̀ ọba Siria láti bá a dá majẹmu alaafia; ṣugbọn agbára ọmọbinrin náà yóo dínkù, ọba pàápàá ati ọmọ rẹ̀ kò sì ní tọ́jọ́. A óo kọ obinrin náà sílẹ̀, òun ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati ọmọ rẹ̀, ati alátìlẹ́yìn rẹ̀.

7. Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ yóo jọba ní ipò rẹ̀, yóo wá pẹlu ogun, yóo wọ ìlú olódi ọba Siria, yóo bá wọn jagun, yóo sì ṣẹgun wọn.

8. Yóo kó àwọn oriṣa wọn, ati àwọn ère wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, pẹlu àwọn ohun èlò olówó iyebíye wọn tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe; kò sì ní bá ọba Siria jagun mọ́ fún ọdún bíi mélòó kan.

9. Ọba Siria yóo wá gbógun ti ọba Ijipti, ṣugbọn yóo sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀.

10. “Àwọn ọmọ ọba Siria yóo gbá ogun ńlá jọ, wọn yóo sì kó ogun wọn wá, wọn yóo jà títí wọn yóo fi wọ ìlú olódi ti ọ̀tá wọn.

11. Inú yóo bí ọba Ijipti, yóo sì lọ bá ọba Siria jagun. Ọba Siria yóo kó ọpọlọpọ ogun jọ, ṣugbọn Ijipti yóo ṣẹgun rẹ̀.

12. Ọba Ijipti óo máa gbéraga nítorí ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí ọpọlọpọ ogun yìí, yóo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun, ṣugbọn kò ní borí.

13. “Nítorí pé ọba Siria yóo tún pada lọ, yóo kó ogun jọ, tí yóo pọ̀ ju ti iṣaaju lọ. Nígbà tí ó bá yá, lẹ́yìn ọpọlọpọ ọdún, yóo pada wá pẹlu ikọ̀ ọmọ ogun tí ó lágbára, pẹlu ọpọlọpọ ihamọra ati ohun ìjà.

14. Ní àkókò náà, ọ̀pọ̀ eniyan yóo dìde sí ọba Ijipti; àwọn oníjàgídíjàgan láàrin àwọn eniyan rẹ̀ yóo dìde kí ìran yìí lè ṣẹ; ṣugbọn wọn kò ní borí.

15. Ọba Siria yóo wá dóti ìlú olódi kan, yóo sì gbà á. Àwọn ọmọ ogun Ijipti kò ní lágbára láti dojú ìjà kọ ọ́, àwọn akikanju wọn pàápàá kò ní lágbára mọ́ láti jagun.

Ka pipe ipin Daniẹli 11