Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 9:9-22 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Wọn óo sì dáhùn pé, ‘Ìdí tí OLUWA fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, àwọn eniyan náà kọ OLUWA Ọlọrun wọn, tí ó kó àwọn baba ńlá wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n sì lọ ń forí balẹ̀ fún àwọn oriṣa, wọ́n ń sìn wọ́n; nítorí náà ni OLUWA fi jẹ́ kí ibi ó bá wọn.’ ”

10. Lẹ́yìn ogún ọdún tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀,

11. tí Hiramu, ọba Tire sì ti fún un ní ìwọ̀n igi kedari, igi sipirẹsi ati wúrà tí ó fẹ́, fún iṣẹ́ náà, Solomoni fún Hiramu ní ogún ìlú ní agbègbè Galili.

12. Ṣugbọn nígbà tí Hiramu ọba wá láti Tire tí ó rí àwọn ìlú tí Solomoni fún un, wọn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn rárá.

13. Ó bi Solomoni pé, “Arakunrin mi, irú àwọn ìlú wo ni o fún mi yìí?” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ilẹ̀ náà ní Kabulu títí di òní olónìí.

14. Ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà ni Hiramu ti fi ranṣẹ sí Solomoni ọba.

15. Pẹlu ipá ni Solomoni ọba fi kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́, tí ó fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀, ó sì kọ́ Milo, ati odi Jerusalẹmu, ati ìlú Hasori, ìlú Megido ati ìlú Geseri.

16. (Farao, ọba Ijipti ti gbógun ti ìlú Geseri ó sì dáná sun ún, ó pa gbogbo àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé inú rẹ̀. Ó fi ìlú náà ṣe ẹ̀bùn igbeyawo fún ọmọ rẹ̀ obinrin, nígbà tí ó fẹ́ Solomoni ọba.

17. Nítorí náà ni Solomoni ṣe tún ìlú náà kọ́.) Pẹlu apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni,

18. ati ìlú Baalati, ati Tamari tí ó wà ní aṣálẹ̀ Juda,

19. ati àwọn ìlú tí ó ń kó àwọn ohun èlò rẹ̀ pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí ó ń kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ń gbé, ati gbogbo ilé yòókù tí ó wu Solomoni láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lẹbanoni, ati ní àwọn ibòmíràn ninu ìjọba rẹ̀.

20. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù lára àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, àwọn tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli–

21. arọmọdọmọ wọn tí wọ́n ṣẹ́kù, tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè parun, ni Solomoni kó lẹ́rú pẹlu ipá, wọ́n sì wà bẹ́ẹ̀ títí di òní yìí.

22. Ṣugbọn Solomoni kò fi àwọn ọmọ Israẹli ṣe ẹrú. Àwọn ni ó ń lò gẹ́gẹ́ bí ọmọ ogun, ati olórí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀; àwọn ni balogun rẹ̀, ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀; àwọn ni ọ̀gá àwọn tí ń darí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ ati àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 9