Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 9:2-20 BIBELI MIMỌ (BM)

2. OLUWA tún fi ara hàn án lẹẹkeji, bí ó ti fara hàn án ní Gibeoni,

3. ó wí fún un pé, “Mo ti gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ, mo sì ti ya ilé tí o kọ́ yìí sí mímọ́. Ibẹ̀ ni wọn óo ti máa sìn mí títí lae. N óo máa mójú tó o, n óo sì máa dáàbò bò ó nígbà gbogbo.

4. Bí o bá sìn mí tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú, gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ, ti ṣe, bí o bá ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o sì pa òfin ati ìlànà mi mọ́,

5. n óo fìdí ìjọba rẹ múlẹ̀ ní Israẹli, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, pé arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo máa jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli títí lae.

6. Ṣugbọn bí ìwọ tabi arọmọdọmọ rẹ bá yapa kúrò lẹ́yìn mi, tí ẹ bá ṣe àìgbọràn sí àwọn òfin ati ìlànà tí mo fi lélẹ̀ fún yín, tí ẹ bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa,

7. n óo mú àwọn ọmọ Israẹli kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún wọn, n óo sì kọ ilé ìsìn tí mo ti yà sí mímọ́ fún orúkọ mi sílẹ̀. Gbogbo ọmọ Israẹli yóo di ẹni àmúpòwe ati ẹlẹ́yà láàrin àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.

8. Ilé yìí yóo di òkìtì àlàpà, yóo sì di ohun àwòyanu ati ẹ̀gàn fún gbogbo ẹni tí ó bá ń rékọjá lọ. Wọn óo máa bi ara wọn léèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí ati ilé yìí?’

9. Wọn óo sì dáhùn pé, ‘Ìdí tí OLUWA fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, àwọn eniyan náà kọ OLUWA Ọlọrun wọn, tí ó kó àwọn baba ńlá wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti sílẹ̀, wọ́n sì lọ ń forí balẹ̀ fún àwọn oriṣa, wọ́n ń sìn wọ́n; nítorí náà ni OLUWA fi jẹ́ kí ibi ó bá wọn.’ ”

10. Lẹ́yìn ogún ọdún tí Solomoni fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀,

11. tí Hiramu, ọba Tire sì ti fún un ní ìwọ̀n igi kedari, igi sipirẹsi ati wúrà tí ó fẹ́, fún iṣẹ́ náà, Solomoni fún Hiramu ní ogún ìlú ní agbègbè Galili.

12. Ṣugbọn nígbà tí Hiramu ọba wá láti Tire tí ó rí àwọn ìlú tí Solomoni fún un, wọn kò tẹ́ ẹ lọ́rùn rárá.

13. Ó bi Solomoni pé, “Arakunrin mi, irú àwọn ìlú wo ni o fún mi yìí?” Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń pe ilẹ̀ náà ní Kabulu títí di òní olónìí.

14. Ọgọfa (120) ìwọ̀n talẹnti wúrà ni Hiramu ti fi ranṣẹ sí Solomoni ọba.

15. Pẹlu ipá ni Solomoni ọba fi kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́, tí ó fi kọ́ ilé OLUWA ati ààfin rẹ̀, ó sì kọ́ Milo, ati odi Jerusalẹmu, ati ìlú Hasori, ìlú Megido ati ìlú Geseri.

16. (Farao, ọba Ijipti ti gbógun ti ìlú Geseri ó sì dáná sun ún, ó pa gbogbo àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé inú rẹ̀. Ó fi ìlú náà ṣe ẹ̀bùn igbeyawo fún ọmọ rẹ̀ obinrin, nígbà tí ó fẹ́ Solomoni ọba.

17. Nítorí náà ni Solomoni ṣe tún ìlú náà kọ́.) Pẹlu apá ìsàlẹ̀ Beti Horoni,

18. ati ìlú Baalati, ati Tamari tí ó wà ní aṣálẹ̀ Juda,

19. ati àwọn ìlú tí ó ń kó àwọn ohun èlò rẹ̀ pamọ́ sí, ati àwọn ìlú tí ó ń kó kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ sí, ati àwọn ìlú tí àwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ ń gbé, ati gbogbo ilé yòókù tí ó wu Solomoni láti kọ́ ní Jerusalẹmu, ní Lẹbanoni, ati ní àwọn ibòmíràn ninu ìjọba rẹ̀.

20. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n ṣẹ́kù lára àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Hifi ati àwọn ará Jebusi, àwọn tí kì í ṣe ara àwọn ọmọ Israẹli–

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 9