Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 8:52-66 BIBELI MIMỌ (BM)

52. “OLUWA Ọlọrun, fi ojurere wo àwa iranṣẹ rẹ, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, kí o sì gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

53. OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni o yà wọ́n sọ́tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé, pé kí wọ́n jẹ́ ìní rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti sọ fún wọn láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ, nígbà tí ó kó àwọn baba ńlá wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.”

54. Nígbà ti Solomoni parí adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí OLUWA, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ níbi tí ó kúnlẹ̀ sí, tí ó sì gbé ọwọ́ sókè.

55. Ó dìde dúró, ó sì súre fún gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ó gbadura sókè pé,

56. “Ìyìn ni fún OLUWA, tí ó fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Ó ti mú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ̀, ṣẹ.

57. Kí OLUWA Ọlọrun wa kí ó wà pẹlu wa, bí ó ti wà pẹlu àwọn baba ńlá wa; kí ó má fi wá sílẹ̀, kí ó má sì kọ̀ wá sílẹ̀,

58. kí ó ṣe wá ní ẹni tí yóo gbọ́ràn sí òun lẹ́nu, kí á lè máa tọ ọ̀nà rẹ̀, kí á lè máa pa àwọn òfin ati ìlànà rẹ̀ tí ó fi fún àwọn baba ńlá wa mọ́.

59. Kí OLUWA Ọlọrun wa ranti adura mi yìí ati gbogbo ẹ̀bẹ̀ tí mo bẹ̀ níwájú rẹ̀ yìí tọ̀sán-tòru, kí ó máa ti èmi iranṣẹ rẹ̀ lẹ́yìn nígbà gbogbo, ati àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀ pẹlu; máa tì wá lẹ́yìn bí ó bá ti tọ́ lojoojumọ,

60. kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé lè mọ̀ pé OLUWA ni Ọlọrun, ati pé kò sí ẹlòmíràn mọ́.

61. Ẹ fi tọkàntọkàn jẹ́ olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ẹ tẹ̀lé ìlànà rẹ̀, kí ẹ sì máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ bí ẹ ti ń ṣe lónìí.”

62. Lẹ́yìn náà, Solomoni ọba ati gbogbo àwọn eniyan rú ẹbọ sí OLUWA.

63. Solomoni fi ọ̀kẹ́ kan ati ẹgbaa (22,000) mààlúù, ati ọ̀kẹ́ mẹfa (120,000) aguntan rú ẹbọ alaafia sí OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni òun ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe ya ilé OLUWA náà sí mímọ́.

64. Ní ọjọ́ kan náà, ọba ya ààrin gbùngbùn àgbàlá tí ó wà níwájú ilé ìsìn sí mímọ́. Níbẹ̀ ni ó ti rú ẹbọ sísun, ati ẹbọ ohun jíjẹ, ati ti ọ̀rá ẹran tí ó fi rú ẹbọ alaafia; nítorí pé pẹpẹ bàbà tí ó wà níwájú OLUWA kéré jù fún àpapọ̀ gbogbo àwọn ẹbọ wọnyi.

65. Solomoni ati àwọn ọmọ Israẹli ṣe Àjọ̀dún Àgọ́ Àjọ níbẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan láti Ẹnu Ọ̀nà Hamati títí dé odò kékeré Ijipti ni wọ́n péjọ níwájú OLUWA fún ọjọ́ meje.

66. Ní ọjọ́ kẹjọ Solomoni tú àwọn eniyan náà ká lọ sí ilé wọn. Gbogbo wọn ni wọ́n súre fún ọba, wọ́n sì pada sílé pẹlu inú dídùn; nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún Dafidi, iranṣẹ rẹ̀, ati fún àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 8