Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 8:48-57 BIBELI MIMỌ (BM)

48. tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn tí ó kó wọn lẹ́rú, tí wọ́n bá kọjú sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn, ati ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ ní orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura sí ọ;

49. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn.

50. Dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, ati gbogbo àìdára tí wọ́n ṣe, kí o sì jẹ́ kí àwọn tí wọ́n kó wọn lẹ́rú ṣàánú wọn.

51. Eniyan rẹ sá ni wọ́n, ìwọ ni o sì ni wọ́n, ìwọ ni o kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná janjan bí iná ìléru.

52. “OLUWA Ọlọrun, fi ojurere wo àwa iranṣẹ rẹ, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, kí o sì gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

53. OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni o yà wọ́n sọ́tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé, pé kí wọ́n jẹ́ ìní rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti sọ fún wọn láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ, nígbà tí ó kó àwọn baba ńlá wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.”

54. Nígbà ti Solomoni parí adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí OLUWA, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ níbi tí ó kúnlẹ̀ sí, tí ó sì gbé ọwọ́ sókè.

55. Ó dìde dúró, ó sì súre fún gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ó gbadura sókè pé,

56. “Ìyìn ni fún OLUWA, tí ó fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Ó ti mú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ̀, ṣẹ.

57. Kí OLUWA Ọlọrun wa kí ó wà pẹlu wa, bí ó ti wà pẹlu àwọn baba ńlá wa; kí ó má fi wá sílẹ̀, kí ó má sì kọ̀ wá sílẹ̀,

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 8