tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn tí ó kó wọn lẹ́rú, tí wọ́n bá kọjú sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn, ati ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ ní orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura sí ọ;