Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 8:45-56 BIBELI MIMỌ (BM)

45. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ọ̀run wá, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn.

46. “Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, (nítorí pé kò sí ẹni tí kì í dẹ́ṣẹ̀), tí o bá bínú sí wọn, tí o sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá ṣẹgun wọn, tí wọ́n sì kó wọn lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ mìíràn, kì báà jẹ́ ibi tí ó jìnnà tabi tòsí,

47. bí wọ́n bá ronupiwada ní ilẹ̀ tí wọ́n kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọ, tí wọ́n bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá, ati ìwà burúkú tí wọ́n hù,

48. tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ní ilẹ̀ àwọn ọ̀tá wọn tí ó kó wọn lẹ́rú, tí wọ́n bá kọjú sí ilẹ̀ tí o fi fún àwọn baba ńlá wọn, ati ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ ní orúkọ rẹ, tí wọ́n bá gbadura sí ọ;

49. gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì tì wọ́n lẹ́yìn.

50. Dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, ati gbogbo àìdára tí wọ́n ṣe, kí o sì jẹ́ kí àwọn tí wọ́n kó wọn lẹ́rú ṣàánú wọn.

51. Eniyan rẹ sá ni wọ́n, ìwọ ni o sì ni wọ́n, ìwọ ni o kó wọn jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná janjan bí iná ìléru.

52. “OLUWA Ọlọrun, fi ojurere wo àwa iranṣẹ rẹ, àní àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, kí o sì gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ wọn nígbàkúùgbà tí wọ́n bá ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́.

53. OLUWA Ọlọrun, ìwọ ni o yà wọ́n sọ́tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé, pé kí wọ́n jẹ́ ìní rẹ, gẹ́gẹ́ bí o ti sọ fún wọn láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ, nígbà tí ó kó àwọn baba ńlá wa jáde ní ilẹ̀ Ijipti.”

54. Nígbà ti Solomoni parí adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí OLUWA, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ níbi tí ó kúnlẹ̀ sí, tí ó sì gbé ọwọ́ sókè.

55. Ó dìde dúró, ó sì súre fún gbogbo ìjọ ọmọ Israẹli, ó gbadura sókè pé,

56. “Ìyìn ni fún OLUWA, tí ó fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ìlérí rẹ̀. Ó ti mú gbogbo ìlérí rere rẹ̀ tí ó ṣe láti ẹnu Mose, iranṣẹ rẹ̀, ṣẹ.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 8