Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 7:35-44 BIBELI MIMỌ (BM)

35. A mọ ìgbátí yíká òkè àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà, tí ó ga sókè ní ààbọ̀ igbọnwọ, ìgbátí yìí wà ní téńté orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe òun ati ìtẹ́dìí rẹ̀.

36. Ó ya àwòrán àwọn kerubu, ati kinniun ati ti igi ọ̀pẹ sí orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ ati ìtẹ́dìí yìí, bí ààyè ti wà fún olukuluku sí; ó sì ṣe òdòdó sí i yípo.

37. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá, bákan náà ni ó da gbogbo wọn, bákan náà ni wọ́n tó, bákan náà ni wọn sì rí.

38. Ó ṣe abọ́ bàbà ńlá mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan gba igba galọọnu, ó sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin. Abọ́ kọ̀ọ̀kan sì wà lórí ìtẹ̀lẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá.

39. Ó to ìtẹ́lẹ̀ marun-un marun-un sí apá ìhà gúsù ati apá ìhà àríwá ilé náà, ó sì gbé agbada omi sí igun tí ó wà ní agbedemeji ìhà gúsù ati ìhà ìlà oòrùn ilé náà.

40. Huramu mọ ọpọlọpọ ìkòkò, ó fi irin rọ ọkọ́ pupọ, ó sì ṣe àwọn àwo kòtò. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe parí iṣẹ́ tí ó bá Solomoni ọba ṣe ninu ilé OLUWA.

41. Àwọn iṣẹ́ náà nìwọ̀nyí: Òpó meji, ati àwọn ọpọ́n rìbìtì rìbìtì meji tí ó wà lórí àwọn òpó náà, ati iṣẹ́ ọnà tí ó ṣe sí ara àwo meji tí ó wà lórí ọpọ́n.

42. Àwọn irinwo pomegiranate tí wọ́n tò sí ìlà meji yí ọpọ́n bìrìkìtì bìrìkìtì orí àwọn òpó náà ká, ní ọgọọgọrun-un.

43. Ó ṣe agbada omi mẹ́wàá ati ìtẹ́dìí kọ̀ọ̀kan fún wọn.

44. Ó ṣe agbada omi ńlá kan ati àwọn ère mààlúù mejila tí wọ́n wà ní abẹ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 7