Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 7:3-18 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Wọ́n to àwọn òpó, tí wọ́n kọ́ ilé yìí lé lórí, ní ìlà mẹta. Òpó mẹẹdogun mẹẹdogun wà ní ìlà kọ̀ọ̀kan. Wọ́n wá na ìtì igi kedari lé àwọn òpó náà lórí.

4. Ìlà mẹta mẹta ni wọ́n to fèrèsé sí, àwọn fèrèsé ilé náà kọjú sí ara wọn ní àgbékà mẹta.

5. Onígun mẹrin ni wọ́n ṣe férémù tí wọ́n fi ṣe àwọn ẹnu ọ̀nà ati fèrèsé ilé náà, wọ́n to àwọn fèrèsé ní ìlà mẹta mẹta ninu ògiri, ni àgbékà àgbékà, lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji ilé náà; wọ́n dojú kọ ara wọn.

6. Ó kọ́ gbọ̀ngàn kan tí ó sọ ní gbọ̀ngàn Olópòó. Gígùn rẹ̀ jẹ́ aadọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ. Ó ní ìloro kan tí wọ́n kọ́ sórí òpó; wọ́n ta nǹkan bò ó lórí.

7. Ó kọ́ gbọ̀ngàn ìtẹ́ kan, níbi tí yóo ti máa dájọ́; igi kedari ni wọ́n fi ṣe ara ògiri rẹ̀ láti òkè délẹ̀.

8. Ó kọ́ ilé tí òun alára óo máa gbé sí àgbàlá tí ó wà lẹ́yìn gbọ̀ngàn bí ó ti kọ́ àwọn ilé yòókù; ó sì kọ́ irú gbọ̀ngàn yìí gan-an fún ọmọ ọba Farao tí ó gbé ní iyawo.

9. Òkúta olówó ńlá, tí wọ́n fi ayùn gé tinú-tẹ̀yìn, ni wọ́n fi kọ́ gbogbo ilé ati àgbàlá rẹ̀, láti ìpìlẹ̀ títí dé òrùlé rẹ̀, ati láti àgbàlá ilé OLUWA títí dé àgbàlá ńlá náà.

10. Òkúta ńláńlá, olówó ńláńlá, onígbọ̀nwọ́ mẹjọ ati onígbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ni wọ́n fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé náà.

11. Òkúta olówó ńlá tí a wọ̀n kí á tó gé e, ati igi kedari, ni wọ́n fi ṣe ògiri rẹ̀.

12. Ìlè mẹta mẹta òkúta gbígbẹ́ tí a fi ìlé kan igi kedari là láàrin, ni wọ́n fi kọ́ àgbàlá ńlá náà yípo. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni àgbàlá ti inú ilé OLUWA ati yàrá àbáwọlé.

13. Solomoni ọba ranṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Huramu wá láti Tire,

14. ará Tire ni baba rẹ̀, ṣugbọn opó ọmọ ẹ̀yà Nafutali kan ni ìyá rẹ̀. Baba rẹ̀ ti jáde láyé, ṣugbọn nígbà ayé rẹ̀, òun náà mọ iṣẹ́ àgbẹ̀dẹ bàbà dáradára. Huramu gbọ́n, ó lóye, ó sì mọ bí a tíí fi idẹ ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà. Ó tọ Solomoni lọ, ó sì bá a ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀.

15. Ó fi bàbà ṣe òpó meji; gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlogun, àyíká rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mejila, ó ní ihò ninu, nínípọn rẹ̀ sì jẹ́ ìka mẹrin. Bákan náà ni òpó keji.

16. Ó sì rọ ọpọ́n bàbà meji, ó gbé wọn ka orí àwọn òpó náà. Gíga àwọn ọpọ́n náà jẹ́ igbọnwọ marun-un marun-un.

17. Ó fi irin hun àwọ̀n meji fún àwọn ọpọ́n orí mejeeji tí wọ́n wà lórí àwọn òpó náà, àwọ̀n kọ̀ọ̀kan fún ọpọ́n orí òpó kọ̀ọ̀kan.

18. Bákan náà ni ó ṣe èso pomegiranate ní ìlà meji, ó fi wọ́n yí iṣẹ́ ọnà àwọ̀n náà po, ó sì fi dárà sí ọpọ́n tí ó wà lórí òpó. Bákan náà ni ó ṣe sí ọpọ́n orí òpó keji.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 7