Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 7:26-35 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Agbada náà nípọn ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Etí rẹ̀ dàbí etí ife omi, ó tẹ̀ ní àtẹ̀sóde bí ìsàlẹ̀ òdòdó lílì. Agbada náà lè gbà tó ẹgbaa (2,000) galọọnu omi.

27. Huramu tún fi bàbà ṣe ìtẹ́lẹ̀ mẹ́wàá, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gùn ní igbọnwọ mẹrin, wọ́n fẹ̀ ní igbọnwọ mẹrin, wọ́n sì ga ní igbọnwọ mẹta.

28. Báyìí ni wọ́n ṣe mọ àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà: wọ́n ní ìtẹ́dìí, àwọn ìtẹ́dìí yìí sì ní igun mẹrin mẹrin,

29. lórí àwọn ìtẹ́dìí yìí ni ó ya àwòrán àwọn kinniun, mààlúù ati ti kerubu sí. Wọ́n ṣe àwọn ọnà róbótó róbótó kan báyìí sí òkè àwọn kinniun ati akọ mààlúù náà ati sí ìsàlẹ̀ wọn.

30. Olukuluku ìtẹ́lẹ̀ yìí ni ó ní àgbá kẹ̀kẹ́ idẹ mẹrin, igun mẹrẹẹrin rẹ̀ sì ní ìtẹ́lẹ̀, lábẹ́ agbada náà ni àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí a rọ wà. A ṣe ọ̀ṣọ́ sí gbogbo igun ìtẹ́lẹ̀ náà,

31. òkè agbada náà dàbí adé tí a yọ sókè ní igbọnwọ kan, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ọnà aláràbarà yí etí rẹ̀ po.

32. Àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrẹẹrin wà lábẹ́ àwọn ìtẹ́dìí yìí, àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́lẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn ọ̀pá inú àgbá kẹ̀kẹ́ náà. Gíga àgbá kẹ̀kẹ́ kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ igbọnwọ kan ààbọ̀.

33. Ó ṣe àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ yìí bíi ti kẹ̀kẹ́ ogun, dídà ni wọ́n dà á ati irin tí àgbá náà fi ń yí, ati riimu wọn, ati sipoku ati họọbu wọn.

34. Ìtẹ́lẹ̀ mẹrin mẹrin ló wà ní orígun mẹrẹẹrin àwọn ìtẹ́dìí náà, ẹyọ kan náà ni wọ́n ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ pẹlu ìtẹ́dìí yìí.

35. A mọ ìgbátí yíká òkè àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà, tí ó ga sókè ní ààbọ̀ igbọnwọ, ìgbátí yìí wà ní téńté orí àwọn ìtẹ́lẹ̀ náà. Àṣepọ̀ ni wọ́n ṣe òun ati ìtẹ́dìí rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 7