Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 7:20-26 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ọpọ́n kọ̀ọ̀kan wà lórí òpó mejeeji, lórí ibi tí ó yọ jáde tí ó rí bìrìkìtì lára àwọn òpó, lẹ́gbẹ̀ẹ́ iṣẹ́ ọnà náà. Igba èso pomegiranate ni wọ́n fi yí àwọn òpó náà ká ní ọ̀nà meji. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe sí òpó keji pẹlu.

21. Ó ri àwọn òpó mejeeji yìí sí àbáwọ Tẹmpili, wọ́n ri ọ̀kan sí ìhà gúsù, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Jakini; wọ́n ri ekeji sí apá àríwá, wọ́n sì pè é ní Boasi.

22. Iṣẹ́ ọnà ìtànná lílì ni wọ́n ṣe sára àwọn òpó náà.Bẹ́ẹ̀ ni iṣẹ́ ṣe parí lórí àwọn òpó náà.

23. Ó ṣe agbada omi rìbìtì kan. Jíjìn rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un ààbọ̀, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹ́wàá. Àyíká rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ.

24. Wọ́n fi idẹ ṣe ọpọlọpọ agbè, wọ́n tò wọ́n ní ìlà meji sí etí agbada omi náà. Láti ilẹ̀ ni wọ́n ti ṣe àwọn agbè yìí ní àṣepọ̀ mọ́ agbada omi náà.

25. Wọ́n gbé agbada yìí ka orí akọ mààlúù mejila, tí wọ́n fi bàbà ṣe. Mẹta ninu àwọn mààlúù náà dojú kọ apá ìhà àríwá, àwọn mẹta dojú kọ apá ìwọ̀ oòrùn, àwọn mẹta dojú kọ apá gúsù, àwọn mẹta sì dojú kọ apá ìlà oòrùn.

26. Agbada náà nípọn ní ìwọ̀n ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan. Etí rẹ̀ dàbí etí ife omi, ó tẹ̀ ní àtẹ̀sóde bí ìsàlẹ̀ òdòdó lílì. Agbada náà lè gbà tó ẹgbaa (2,000) galọọnu omi.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 7