Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 6:2-18 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Gígùn ilé tí Solomoni kọ́ fún OLUWA jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ìbú rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ.

3. Yàrá àbáwọlé ilé ìsìn náà gùn ní ogún igbọnwọ, gígùn rẹ̀ ṣe déédé pẹlu ìbú rẹ̀, ó sì jìn sí ìsàlẹ̀ ní igbọnwọ mẹ́wàá níwájú.

4. Ògiri ilé ìsìn náà ní àwọn fèrèsé tí wọ́n fẹ̀ ninu ju bí wọ́n ti fẹ̀ lóde lọ.

5. Wọ́n kọ́ ilé alágbèékà mẹta mọ́ ara ògiri ilé ìsìn náà yípo lọ́wọ́ òde, ati gbọ̀ngàn ti òde, ati ibi mímọ́ ti inú; wọ́n sì kọ́ yàrá ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ sí i yípo. Gíga àgbékà kọ̀ọ̀kan ilé náà jẹ́ igbọnwọ marun-un;

6. ilé ti ìsàlẹ̀ fẹ̀ ní igbọnwọ marun-un; àgbékà ti ààrin fẹ̀ ní igbọnwọ mẹfa, àgbékà ti òkè patapata fẹ̀ ní igbọnwọ meje. Ògiri àgbékà tí ó wà ní òkè patapata kò nípọn tó ti èyí tí ó wà ní ààrin, ti ààrin kò sì nípọn tó ti èyí tí ó wà ní ìsàlẹ̀ patapata; tí ó fi jẹ́ pé àwọn yàrá náà lè jókòó lórí ògiri láìfi òpó gbé wọn ró.

7. Níbi tí wọ́n ti ń fọ́ òkúta ni wọ́n ti gbẹ́ gbogbo òkúta tí wọ́n fi kọ́ ilé ìsìn náà, wọn kò lo òòlù, tabi àáké, tabi ohun èlò irin kankan ninu tẹmpili náà nígbà tí wọ́n ti ń kọ́ ọ lọ.

8. Ninu ilé alágbèékà mẹta tí wọ́n kọ́ mọ́ ara ilé ìsìn náà, ẹnu ọ̀nà ilé tí ó wà ní ìsàlẹ̀ patapata wà ní apá gúsù ilé ìsìn náà, ó ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà keji, àgbékà keji sì ní àtẹ̀gùn tí ó lọ sí àgbékà kẹta.

9. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ọba ṣe kọ́ ilé ìsìn náà parí, ó sì fi ọ̀pá àjà ati pákó igi kedari ṣe àjà rẹ̀.

10. Ara ògiri ilé ìsìn náà níta ni wọ́n kọ́ ilé alágbèékà mẹta yìí mọ́, àgbékà kọ̀ọ̀kan ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n sì fi pákó igi kedari so wọ́n pọ̀ mọ́ ara ilé ìsìn náà.

11. OLUWA wí fún Solomoni ọba pé,

12. “Ní ti ilé ìsìn tí ò ń kọ́ yìí, bí o bá pa gbogbo òfin mi mọ́, tí o sì tẹ̀lé ìlànà mi, n óo ṣe gbogbo ohun tí mo ṣèlérí fún Dafidi, baba rẹ, fún ọ.

13. N óo máa gbé ààrin àwọn ọmọ Israẹli, n kò sì ní kọ eniyan mi sílẹ̀ laelae.”

14. Bẹ́ẹ̀ ni Solomoni ṣe parí kíkọ́ ilé ìsìn náà.

15. Pákó igi kedari ni ó fi bo ara ògiri ilé náà ninu, láti òkè dé ilẹ̀. Pákó igi sipirẹsi ni wọ́n sì fi tẹ́ gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

16. Wọ́n kọ́ yàrá kan tí wọn ń pè ní Ibi-Mímọ́-Jùlọ, sí ọwọ́ ẹ̀yìn ilé ìsìn náà. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún igbọnwọ, pákó kedari ni wọn fi gé e láti òkè dé ilẹ̀.

17. Gbọ̀ngàn tí ó wà níwájú Ibi-Mímọ́-Jùlọ yìí gùn ní ogoji igbọnwọ.

18. Wọ́n gbẹ́ àwòrán agbè ati òdòdó, wọ́n fi ṣe ọ̀ṣọ́ sára igi kedari tí wọ́n fi bo ògiri gbọ̀ngàn náà, òkúta tí wọ́n fi mọ ògiri ilé náà kò sì hàn síta rárá.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 6