Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 4:12-27 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Baana, ọmọ Ahiludi, ni alákòóso ìlú Taanaki, ati ti Megido, ati gbogbo agbègbè Beti Ṣeani, lẹ́bàá ìlú Saretani, ní ìhà gúsù Jesireeli ati Beti Ṣeani; títí dé ìlú Abeli Mehola títí dé òdìkejì Jokimeamu.

13. Bẹngeberi ni alákòóso ìlú Ramoti Gileadi, (ati àwọn ìletò Jairi, ọmọ Manase, tí ó wà ní ilẹ̀ Gileadi, ati agbègbè Arigobu, ní ilẹ̀ Baṣani. Gbogbo wọn jẹ́ ọgọta ìlú ńláńlá tí wọn mọ odi yíká, bàbà ni wọ́n sì fi ṣe ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn ẹnubodè wọn.)

14. Ahinadabu, ọmọ Ido ni alákòóso agbègbè Mahanaimu.

15. Ahimaasi, (ọkọ Basemati, ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Solomoni), ni alákòóso Nafutali.

16. Baana, ọmọ Huṣai, ni alákòóso agbègbè Aṣeri, ati Bealoti.

17. Jehoṣafati, ọmọ Parua, ni alákòóso agbègbè Isakari.

18. Ṣimei, ọmọ Ela, ni alákòóso agbègbè Bẹnjamini.

19. Geberi, ọmọ Uri, ni alákòóso agbègbè Gileadi, níbi tí Sihoni ọba àwọn ará Amori ati Ogu ọba Baṣani ti jọba tẹ́lẹ̀ rí.Lẹ́yìn àwọn alákòóso mejeejila wọnyi, alákòóso àgbà kan tún wà fún gbogbo ilẹ̀ Juda.

20. Àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ bíi yanrìn inú òkun, wọ́n ń rí jẹ, wọ́n ń rí mu, wọ́n sì láyọ̀.

21. Solomoni jọba lórí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, láti odò Yufurate títí dé ilẹ̀ Filistia, títí dé ààlà ilẹ̀ àwọn ará Ijipti. Wọ́n ń san ìṣákọ́lẹ̀ fún un, wọ́n sì ń sìn ín ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

22. Àwọn nǹkan tí Solomoni ń lò fún ìtọ́jú oúnjẹ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan nìwọ̀nyí: Ọgbọ̀n òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun tí ó kúnná dáradára, ati ọgọta òṣùnwọ̀n ọkà tí wọ́n lọ̀;

23. àbọ́pa mààlúù mẹ́wàá, ogún mààlúù tí wọn ń dà ninu pápá, ati ọgọrun-un aguntan; láìka àgbọ̀nrín, egbin, ìgalà, ati oríṣìíríṣìí ẹyẹ àbọ́pa.

24. Solomoni jọba lórí gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate, láti ìlú Tifisa, títí dé ìlú Gasa, ati lórí gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà ní apá ìwọ̀ oòrùn odò Yufurate; alaafia sì wà láàrin òun ati àwọn agbègbè tí ó wà ní àyíká rẹ̀.

25. Ní gbogbo àkókò Solomoni, gbogbo àwọn ọmọ Juda ati àwọn ọmọ Israẹli wà ní alaafia láti ìlú Dani títí dé Beeriṣeba. Ìdílé kọ̀ọ̀kan ní ọgbà àjàrà ati àwọn igi ọ̀pọ̀tọ́ tirẹ̀.

26. Ọ̀kẹ́ meji (40,000) ni ilé tí Solomoni kọ́ fún àwọn ẹṣin tí ń fa àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì ní ẹgbaafa (12,000) eniyan tí ń gun ẹṣin.

27. Alákòóso kọ̀ọ̀kan níí máa tọ́jú nǹkan jíjẹ tí Solomoni ọba ń lò fún ara rẹ̀ ati fún gbogbo àwọn tí ń jẹun ní ààfin rẹ̀; alákòóso kọ̀ọ̀kan sì ní oṣù tí ó gbọdọ̀ pèsè nǹkan jíjẹ, láìjẹ́ kí ohunkohun dín ninu ohun tí ọba nílò.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 4