Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 22:47-53 BIBELI MIMỌ (BM)

47. Kò sí ọba ní ilẹ̀ Edomu. Adelé ọba kan ní ń ṣàkóso ilẹ̀ náà.

48. Jehoṣafati ọba kan àwọn ọkọ̀ ojú omi bíi ti ìlú Taṣiṣi, láti kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ofiri láti lọ wá wúrà. Ṣugbọn wọn kò lè lọ nítorí pé àwọn ọkọ̀ náà bàjẹ́ ní Esiongeberi.

49. Ahasaya ọba Israẹli, ọmọ Ahabu, ọba Israẹli sọ fún Jehoṣafati pé kí àwọn eniyan òun bá àwọn eniyan rẹ̀ tu ọkọ̀ lọ, ṣugbọn Jehoṣafati kò gbà.

50. Nígbà tí ó yá, Jehoṣafati kú, wọ́n sì sin ín sí ibojì àwọn ọba, ní ìlú Dafidi, baba ńlá rẹ̀. Jehoramu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀.

51. Ní ọdún kẹtadinlogun tí Jehoṣafati, ọba Juda, gun orí oyè ni Ahasaya, ọmọ Ahabu, gun orí oyè ní ilẹ̀ Israẹli, ó sì jọba ní Samaria fún ọdún meji.

52. Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú Ahabu, baba rẹ̀, ati ti Jesebẹli, ìyá rẹ̀, ati ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, àwọn tí wọ́n jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀.

53. Ó bọ oriṣa Baali, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú ní gbogbo ọ̀nà bí baba rẹ̀ ti ṣe.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 22