Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé àpẹẹrẹ burúkú Ahabu, baba rẹ̀, ati ti Jesebẹli, ìyá rẹ̀, ati ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, àwọn tí wọ́n jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀.