Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 22:25-35 BIBELI MIMỌ (BM)

25. Mikaaya bá dá a lóhùn pé, “O óo rí i nígbà tí ó bá di ọjọ́ náà, tí o bá sá wọ yàrá inú patapata lọ, láti fi ara pamọ́.”

26. Ọba Israẹli bá dáhùn pé, “Ẹ mú Mikaaya pada lọ fún Amoni, gomina ìlú yìí, ati Joaṣi ọmọ ọba.

27. Ẹ ní, èmi ọba ni mo ní kí ẹ sọ fún wọn pé, kí wọ́n jù ú sinu ẹ̀wọ̀n, kí wọn sì máa fún un ní àkàrà lásán ati omi, títí tí n óo fi pada dé ní alaafia.”

28. Mikaaya bá dáhùn pé, “Bí o bá pada dé ní alaafia, a jẹ́ pé kì í ṣe OLUWA ló gba ẹnu mi sọ̀rọ̀.” Ó ní, “Gbogbo eniyan, ṣé ẹ gbọ́ ohun tí mo wí?”

29. Ahabu, ọba Israẹli, ati Jehoṣafati, ọba Juda, bá lọ gbógun ti ìlú Ramoti Gileadi.

30. Ahabu wí fún Jehoṣafati pé, “Bí a ti ń lọ sí ojú ogun yìí, n óo paradà, kí ẹnikẹ́ni má baà dá mi mọ̀. Ṣugbọn ìwọ, wọ aṣọ oyè rẹ.” Ahabu, ọba Israẹli, bá paradà, ó sì lọ sójú ogun.

31. Ọba Siria ti pàṣẹ fún àwọn olórí kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ mejeejilelọgbọn, pé kí wọ́n má lépa ẹnikẹ́ni lójú ogun, àfi ọba Israẹli nìkan.

32. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n rí Jehoṣafati ọba, wọ́n ní, “Dájúdájú ọba Israẹli nìyí.” Wọ́n bá yipada láti bá a jà; ṣugbọn Jehoṣafati kígbe.

33. Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé kì í ṣe òun ni ọba Israẹli, wọ́n bá pada lẹ́yìn rẹ̀.

34. Ṣugbọn ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Siria déédé ta ọfà rẹ̀, ọfà náà sì bá Ahabu ọba níbi tí àwọn irin ìgbàyà rẹ̀ ti fi ẹnu ko ara wọn. Ó bá wí fún ẹni tí ń wa kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ pé kí ó gbé òun kúrò lójú ogun, nítorí pé òun ti fara gbọgbẹ́.

35. Ogun gbóná gidigidi ní ọjọ́ náà. Ọwọ́ ni wọ́n fi ti ọba Ahabu ninu kẹ̀kẹ́ ogun tí ó wà, tí ó sì kọjú sí àwọn ará Siria. Nígbà tí yóo sì fi di ìrọ̀lẹ́, ó ti kú. Ẹ̀jẹ̀ tí ń ṣàn láti ojú ọgbẹ́ rẹ̀ sì ti dà sí ìsàlẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun náà.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 22