Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 20:29-41 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti àwọn ọmọ ogun Siria kọjú sí ara wọn, wọn kò sì kúrò ní ààyè wọn fún ọjọ́ meje. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn lára àwọn ti Siria ní ọjọ́ kan.

30. Àwọn ọmọ ogun Siria yòókù sì sá lọ sí ìlú Afeki; odi ìlú náà sì wó pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaarin (27,000) tí ó kù ninu wọn.Benhadadi pàápàá sá wọ inú ìlú lọ, ó sì sá pamọ́ sinu yàrá ní ilé kan.

31. Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “A gbọ́ pé àwọn ọba Israẹli a máa ní ojú àánú, jẹ́ kí á sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, kí á wé okùn mọ́ ara wa lórí, kí á sì lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli, bóyá yóo dá ẹ̀mí rẹ sí.”

32. Nítorí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, wọ́n sì wé okùn mọ́ ara wọn lórí. Wọ́n bá tọ Ahabu ọba lọ, wọ́n ní, “Benhadadi, iranṣẹ rẹ, ní kí á jíṣẹ́ fún ọ pé kí o jọ̀wọ́ kí o dá ẹ̀mí òun sí.”Ahabu bá dáhùn pé, “Ó ṣì wà láàyè? Arakunrin mi ni!”

33. Àwọn iranṣẹ Benhadadi ti ń ṣọ́ Ahabu fún àmì rere kan tẹ́lẹ̀. Nígbà tí Ahabu ti fẹnu kan “Arakunrin”, kíá ni wọ́n ti gba ọ̀rọ̀ yìí mọ́ ọn lẹ́nu, wọ́n ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, arakunrin rẹ ni Benhadadi.”Ahabu wí fún wọn pé, “Ẹ lọ mú un wá.” Nígbà tí Benhadadi dé, Ahabu ní kí ó wọ inú kẹ̀kẹ́ ogun pẹlu òun.

34. Benhadadi bá wí fún un pé, “N óo dá àwọn ìlú tí baba mi gbà lọ́wọ́ baba rẹ pada fún ọ, o óo sì lè kọ́ àwọn ilé ìtajà fún ara rẹ ní ìlú Damasku gẹ́gẹ́ bí baba mi ti ṣe ní ìlú Samaria.”Ahabu dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe ohun tí o wí yìí, n óo dá ọ sílẹ̀.” Ahabu bá bá a dá majẹmu, ó sì fi sílẹ̀ kí ó máa lọ.

35. OLUWA pàṣẹ fún ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wolii kan, pé kí ó sọ fún wolii ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan pé kí ó jọ̀wọ́ kí ó lu òun, ṣugbọn wolii náà kọ̀, kò lù ú.

36. Ni ó bá wí fún un pé, “Nítorí pé o ṣàìgbọràn sí àṣẹ OLUWA, bí o bá ti ń kúrò lọ́dọ̀ mi gẹ́lẹ́ ni kinniun yóo pa ọ́.” Bí ó sì ti kúrò lóòótọ́, kinniun kan yọ sí i, ó sì pa á.

37. Wolii yìí rí ọkunrin mìíràn, o sì bẹ̀ ẹ́ pé, “Lù mí.” Ọkunrin yìí lù ú, lílù náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi pa á lára.

38. Wolii yìí bá mú aṣọ kan, ó fi wé ojú rẹ̀. Ó yíra pada, kí ẹnikẹ́ni má baà mọ̀ ọ́n, ó sì lọ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà de ìgbà tí ọba Israẹli yóo kọjá.

39. Bí ọba ti ń kọjá lọ, wolii yìí kígbe pé, “Kabiyesi, nígbà tí mò ń jà lójú ogun, ọmọ ogun ẹlẹgbẹ́ mi kan mú ọ̀tá kan tí ó mú ní ìgbèkùn wá sọ́dọ̀ mi, ó ní kí n máa ṣọ́ ọkunrin yìí, ó ní bí ó bá sá lọ, èmi ni n óo kú dípò rẹ̀. Bí bẹ́ẹ̀ sì kọ́, mo níláti san ìwọ̀n talẹnti fadaka kan gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.

40. Ṣugbọn níbi tí mo ti ń lọ sókè sódò, tí mò ń ṣe àwọn nǹkan mìíràn, ọkunrin yìí sá lọ.”Ọba dá a lóhùn pé, “Ìwọ náà ti dá ara rẹ lẹ́jọ́, bẹ́ẹ̀ gan-an ni yóo sì rí.”

41. Wolii náà sáré tu aṣọ tí ó fi wé ojú, lẹsẹkẹsẹ ọba sì mọ̀ pé ọ̀kan ninu àwọn wolii ni.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 20