Nítorí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, wọ́n sì wé okùn mọ́ ara wọn lórí. Wọ́n bá tọ Ahabu ọba lọ, wọ́n ní, “Benhadadi, iranṣẹ rẹ, ní kí á jíṣẹ́ fún ọ pé kí o jọ̀wọ́ kí o dá ẹ̀mí òun sí.”Ahabu bá dáhùn pé, “Ó ṣì wà láàyè? Arakunrin mi ni!”