Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 20:13-32 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Wolii kan bá tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Ṣé o rí gbogbo àwọn ọmọ ogun yìí bí wọ́n ti pọ̀ tó? Wò ó! N óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn lónìí, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

14. Ahabu bèèrè pé, “Ta ni yóo ṣáájú ogun?”Wolii náà dáhùn pé, “OLUWA ní, àwọn iranṣẹ gomina ìpínlẹ̀ ni.”Ahabu tún bèèrè pé, “Ta ni yóo bẹ̀rẹ̀ ogun náà?”Wolii náà dáhùn pé, “Ìwọ gan-an ni.”

15. Ọba bá pe gbogbo àwọn iranṣẹ tí wọ́n wà lábẹ́ àwọn gomina ìpínlẹ̀ jọ, gbogbo wọn jẹ́ ojilerugba ó dín mẹjọ (232), ó sì pe gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, gbogbo wọ́n jẹ́ ẹẹdẹgbaarin (7,000).

16. Nígbà tí ó di ọ̀sán, wọ́n kó ogun jáde, bí Benhadadi ọba ati àwọn ọba mejilelọgbọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ti ń mu ọtí àmupara ninu àgọ́ wọn.

17. Àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun Israẹli, wọ́n bá lọ ṣígun bá Benhadadi. Àwọn amí tí ọba Benhadadi rán jáde lọ ròyìn fún un pé, àwọn eniyan kan ń jáde bọ̀ láti ìlú Samaria.

18. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n mú wọn láàyè, wọ́n ìbáà máa bọ̀ wá jagun, wọn ìbáà sì máa bọ̀ wá sọ̀rọ̀ alaafia.

19. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun ṣe jáde ní ìlú: àwọn ọ̀dọ́ ọmọ ogun ni wọ́n ṣáájú ogun, lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun Israẹli tẹ̀lé wọn.

20. Olukuluku wọn pa ẹni tí ó dojú ìjà kọ. Àwọn ọmọ ogun Siria bá sá. Àwọn ọmọ ogun Israẹli sì ń lé wọn lọ. Ṣugbọn Benhadadi, ọba Siria, ti gun ẹṣin sá lọ, pẹlu àwọn jagunjagun tí wọ́n gun ẹṣin.

21. Ahabu ọba bá lọ sójú ogun, ó kó ọpọlọpọ ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun; ó ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Siria, ó sì pa ọpọlọpọ ninu wọn.

22. Wolii náà tún tọ Ahabu ọba lọ, ó wí fún un pé, “Pada lọ kó àwọn ọmọ ogun rẹ jọ, kí o sì ṣètò dáradára; nítorí pé, ọba Siria yóo tún bá ọ jagun ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò.”

23. Àwọn oníṣẹ́ Benhadadi ọba wí fún un pé, “Oriṣa orí òkè ni oriṣa àwọn ọmọ Israẹli. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ṣẹgun wa. Ṣugbọn bí a bá gbógun tì wọ́n ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, a óo ṣẹgun wọn.

24. Nítorí náà, mú àwọn ọba mejeejilelọgbọn kúrò ní ààyè wọn gẹ́gẹ́ bí olórí ogun, kí o sì fi àwọn ọ̀gágun gidi dípò wọn.

25. Kí o wá kó àwọn ọmọ ogun mìíràn jọ, kí wọ́n pọ̀ bí i ti àkọ́kọ́, kí ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun pọ̀ bákan náà. A óo bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní pẹ̀tẹ́lẹ̀; láìsí àní àní, a óo sì ṣẹgun wọn.”Ọba Benhadadi gba ìmọ̀ràn wọn, ó sì ṣe ohun tí wọ́n wí.

26. Ní ọdún tí ó tẹ̀lé e, ní ìbẹ̀rẹ̀ àkókò òjò, ó kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì kó wọn lọ sí ìlú Afeki, láti gbógun ti àwọn ọmọ Israẹli.

27. Wọ́n kó àwọn ọmọ ogun Israẹli náà jọ, wọ́n sì wá àwọn ohun ìjà ogun fún wọn. Àwọn náà jáde sójú ogun, wọ́n pàgọ́ tiwọn siwaju àwọn ọmọ ogun Siria, wọ́n wá dàbí agbo ewúrẹ́ meji kéékèèké níwájú àwọn ọmọ ogun Siria tí wọ́n tò lọ rẹrẹẹrẹ ninu pápá.

28. Wolii kan tọ Ahabu lọ, ó sì wí fún un pé, “OLUWA ní kí n wí fún ọ pé, ‘Nítorí pé àwọn ará Siria sọ pé, “ọlọrun orí òkè ni OLUWA, kì í ṣe Ọlọrun àfonífojì,” nítorí náà ni n óo ṣe fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí ọ̀pọ̀ eniyan wọnyi, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.’ ”

29. Àgọ́ àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti àwọn ọmọ ogun Siria kọjú sí ara wọn, wọn kò sì kúrò ní ààyè wọn fún ọjọ́ meje. Nígbà tí ó di ọjọ́ keje wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jagun. Àwọn ọmọ ogun Israẹli pa ọ̀kẹ́ marun-un (100,000) ọmọ ogun tí wọn ń fi ẹsẹ̀ rìn lára àwọn ti Siria ní ọjọ́ kan.

30. Àwọn ọmọ ogun Siria yòókù sì sá lọ sí ìlú Afeki; odi ìlú náà sì wó pa ọ̀kẹ́ kan ati ẹẹdẹgbaarin (27,000) tí ó kù ninu wọn.Benhadadi pàápàá sá wọ inú ìlú lọ, ó sì sá pamọ́ sinu yàrá ní ilé kan.

31. Àwọn oníṣẹ́ rẹ̀ wí fún un pé, “A gbọ́ pé àwọn ọba Israẹli a máa ní ojú àánú, jẹ́ kí á sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, kí á wé okùn mọ́ ara wa lórí, kí á sì lọ sọ́dọ̀ ọba Israẹli, bóyá yóo dá ẹ̀mí rẹ sí.”

32. Nítorí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́dìí, wọ́n sì wé okùn mọ́ ara wọn lórí. Wọ́n bá tọ Ahabu ọba lọ, wọ́n ní, “Benhadadi, iranṣẹ rẹ, ní kí á jíṣẹ́ fún ọ pé kí o jọ̀wọ́ kí o dá ẹ̀mí òun sí.”Ahabu bá dáhùn pé, “Ó ṣì wà láàyè? Arakunrin mi ni!”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 20