Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 18:39-46 BIBELI MIMỌ (BM)

39. Nígbà tí àwọn eniyan náà rí i, wọ́n dojúbolẹ̀, wọ́n wí pé, “OLUWA ni Ọlọrun! OLUWA ni Ọlọrun!”

40. Elija bá pàṣẹ pé, “Ẹ mú gbogbo àwọn wolii oriṣa Baali! Ẹ má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ninu wọn sá lọ.” Àwọn eniyan náà bá ki gbogbo wọn mọ́lẹ̀, Elija kó wọn lọ sí ibi odò Kiṣoni, ó sì pa wọ́n sibẹ.

41. Lẹ́yìn náà, Elija sọ fún Ahabu ọba pé, “Lọ, jẹun, kí o wá nǹkan mu, nítorí mo gbọ́ kíkù òjò.”

42. Nígbà tí Ahabu lọ jẹun, Elija gun orí òkè Kamẹli lọ, ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó sì ki orí bọ ààrin orúnkún rẹ̀ mejeeji.

43. Ó sọ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ wo apá ìhà òkun.Iranṣẹ náà lọ, ó sì pada wá, ó ní, òun kò rí nǹkankan. Elija sọ fún un pé, “Tún lọ ní ìgbà meje.”

44. Ní ìgbà keje tí ó pada dé, ó ní, “Mo rí ìkùukùu kan tí ń bọ̀ láti inú òkun, ṣugbọn kò ju àtẹ́lẹwọ́ lọ.”Elija pàṣẹ fún iranṣẹ rẹ̀ pé kí ó lọ sọ fún ọba, kí ó kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, kí ó sì sọ̀kalẹ̀ pada sí ilé kí òjò má baà ká a mọ́ ibi tí ó wà.

45. Láìpẹ́, ìkùukùu bo gbogbo ojú ọ̀run, afẹ́fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́, òjò ńlá sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀. Ahabu kó sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sì pada lọ sí Jesireeli.

46. Agbára OLUWA sọ̀kalẹ̀ sórí Elija, ó di àmùrè rẹ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ; ó sì ṣáájú Ahabu dé ẹnubodè Jesireeli.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 18