Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 16:20-34 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Gbogbo nǹkan yòókù tí Simiri ṣe: gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

21. Lẹ́yìn ikú Simiri àwọn ọmọ Israẹli pín sí ọ̀nà meji. Àwọn kan wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati, pé òun ni kí ó jọba. Àwọn yòókù sì wà lẹ́yìn Omiri.

22. Níkẹyìn, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Omiri ṣẹgun àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati. Tibini kú, Omiri sì jọba.

23. Ní ọdún kọkanlelọgbọn tí Asa, ọba Juda ti wà lórí oyè, ni Omiri gorí oyè ní Israẹli. Ó sì jọba fún ọdún mejila. Ìlú Tirisa ni ó gbé fún ọdún mẹfa àkọ́kọ́.

24. Lẹ́yìn náà, ó ra òkè Samaria ní ìwọ̀n talẹnti fadaka meji, lọ́wọ́ ọkunrin kan tí ń jẹ́ Ṣemeri. Omiri mọ odi yí òkè náà ká, ó sì sọ orúkọ ìlú tí ó kọ́ náà ní Samaria, gẹ́gẹ́ bí orúkọ Ṣemeri, ẹni tí ó ni òkè náà tẹ́lẹ̀.

25. Nǹkan tí Omiri ṣe burú lójú OLUWA, ibi tí ó ṣe pọ̀ ju ti gbogbo àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ lọ.

26. Gbogbo ọ̀nà burúkú tí Jeroboamu ọmọ Nebati rìn ni òun náà ń tọ̀. Òun náà jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú nítorí oriṣa tí wọn ń bọ.

27. Àwọn nǹkan yòókù tí Omiri ṣe ati iṣẹ́ akikanju tí ó ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

28. Omiri kú, wọ́n sì sin ín sí Samaria; Ahabu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀.

29. Ní ọdún kejidinlogoji tí Asa, ọba Juda gorí oyè ni Ahabu, ọmọ Omiri gorí oyè ní Israẹli, Ahabu sì jọba lórí Israẹli ní Samaria fún ọdún mejilelogun.

30. Ahabu ọmọ Omiri ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA ju gbogbo àwọn tí wọ́n ṣáájú rẹ̀ lọ.

31. Bí ẹni pé, gbogbo àìdára tí Ahabu ọba ṣe bíi ti Jeroboamu, ọmọ Nebati, kò burú tó, ó tún lọ fẹ́ Jesebẹli ọmọbinrin Etibaali, ọba Sidoni, ó sì ń bọ oriṣa Baali.

32. Ó tẹ́ pẹpẹ kan fún oriṣa Baali ninu ilé tí ó kọ́ fún oriṣa náà, ní Samaria.

33. Bákan náà, ó tún ṣe oriṣa Aṣera kan. Ahabu ṣe ohun tí ó bí OLUWA Ọlọrun Israẹli ninu ju gbogbo àwọn ọba Israẹli tí wọ́n jẹ ṣáájú rẹ̀ lọ.

34. Ní àkókò ìgbà tirẹ̀ ni Hieli ará Bẹtẹli tún ìlú Jẹriko kọ́. Abiramu àkọ́bí rẹ̀ ọkunrin kú, nígbà tí Hieli fi ìpìlẹ̀ ìlú Jẹriko lélẹ̀. Segubu, àbíkẹ́yìn rẹ̀ ọkunrin sì tún kú bákan náà, nígbà tí ó gbé ìlẹ̀kùn sí ẹnubodè rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀, láti ẹnu Joṣua, ọmọ Nuni.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 16