Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 16:10-30 BIBELI MIMỌ (BM)

10. ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa ọba Juda gorí oyè, Simiri bá wọlé, ó fi idà ṣá Ela pa, ó bá fi ara rẹ̀ jọba dípò Ela.

11. Bí Simiri ti gorí oyè, tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jọba ni ó pa gbogbo àwọn ìdílé Baaṣa patapata. Gbogbo àwọn ìbátan ati ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọkunrin ni ó pa láìdá ẹnikẹ́ni sí.

12. Báyìí ni Simiri ṣe pa gbogbo ìdílé Baaṣa, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀, láti ẹnu wolii Jehu,

13. nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí Baaṣa ati Ela ọmọ rẹ̀ dá ati èyí tí wọ́n mú kí Israẹli dá, tí wọ́n mú kí OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú nítorí oriṣa wọn.

14. Gbogbo nǹkan yòókù tí Ela ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

15. Ní ọdún kẹtadinlọgbọn tí Asa jọba ní Juda, Simiri gorí oyè ní Tirisa, ó sì jọba Israẹli fún ọjọ́ meje. Ní àkókò yìí àwọn ọmọ ogun Israẹli gbógun ti ìlú Gibetoni ní ilẹ̀ Filistia.

16. Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé, Simiri ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ati pé ó ti pa á, lẹsẹkẹsẹ ni gbogbo Israẹli fi Omiri olórí ogun, jọba Israẹli ninu àgọ́ wọn ní ọjọ́ náà.

17. Omiri ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá kúrò ní ìlú Gibetoni, wọ́n lọ dó ti ìlú Tirisa.

18. Nígbà tí Simiri rí i pé ọwọ́ ti tẹ ìlú náà, ó lọ sí ibi ààbò tí ó wà ninu ààfin, ó tiná bọ ààfin, ó sì kú sinu iná;

19. nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá, tí ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, tí ó tọ ọ̀nà tí Jeroboamu tọ̀, ati fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó dá: tí ó mú kí àwọn ọmọ Israẹli náà dẹ́ṣẹ̀.

20. Gbogbo nǹkan yòókù tí Simiri ṣe: gbogbo ìwà ọ̀tẹ̀ rẹ̀, ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

21. Lẹ́yìn ikú Simiri àwọn ọmọ Israẹli pín sí ọ̀nà meji. Àwọn kan wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati, pé òun ni kí ó jọba. Àwọn yòókù sì wà lẹ́yìn Omiri.

22. Níkẹyìn, àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Omiri ṣẹgun àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Tibini, ọmọ Ginati. Tibini kú, Omiri sì jọba.

23. Ní ọdún kọkanlelọgbọn tí Asa, ọba Juda ti wà lórí oyè, ni Omiri gorí oyè ní Israẹli. Ó sì jọba fún ọdún mejila. Ìlú Tirisa ni ó gbé fún ọdún mẹfa àkọ́kọ́.

24. Lẹ́yìn náà, ó ra òkè Samaria ní ìwọ̀n talẹnti fadaka meji, lọ́wọ́ ọkunrin kan tí ń jẹ́ Ṣemeri. Omiri mọ odi yí òkè náà ká, ó sì sọ orúkọ ìlú tí ó kọ́ náà ní Samaria, gẹ́gẹ́ bí orúkọ Ṣemeri, ẹni tí ó ni òkè náà tẹ́lẹ̀.

25. Nǹkan tí Omiri ṣe burú lójú OLUWA, ibi tí ó ṣe pọ̀ ju ti gbogbo àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ lọ.

26. Gbogbo ọ̀nà burúkú tí Jeroboamu ọmọ Nebati rìn ni òun náà ń tọ̀. Òun náà jẹ́ kí Israẹli dẹ́ṣẹ̀, ó sì mú OLUWA Ọlọrun Israẹli bínú nítorí oriṣa tí wọn ń bọ.

27. Àwọn nǹkan yòókù tí Omiri ṣe ati iṣẹ́ akikanju tí ó ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

28. Omiri kú, wọ́n sì sin ín sí Samaria; Ahabu ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè dípò rẹ̀.

29. Ní ọdún kejidinlogoji tí Asa, ọba Juda gorí oyè ni Ahabu, ọmọ Omiri gorí oyè ní Israẹli, Ahabu sì jọba lórí Israẹli ní Samaria fún ọdún mejilelogun.

30. Ahabu ọmọ Omiri ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA ju gbogbo àwọn tí wọ́n ṣáájú rẹ̀ lọ.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 16