Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 12:11-20 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Sọ fún wọn pé, ‘Ṣé ẹ sọ pé ẹrù wúwo ni baba mi dì rù yín? Tèmi tí n óo dì rù yín yóo tilẹ̀ tún wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ; ati pé ẹgba ni baba mi fi ń nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.’ ”

12. Jeroboamu ati gbogbo àwọn eniyan náà bá pada wá sọ́dọ̀ Rehoboamu ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí ó ti pàṣẹ fún wọn.

13. Rehoboamu gbójú mọ́ àwọn eniyan náà bí ó ti ń dá wọn lóhùn, ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un,

14. gẹ́gẹ́ bí àwọn ọdọmọkunrin ti gbà á nímọ̀ràn. Ó ní, “Ẹrù wúwo ni ẹ sọ pé baba mi dì rù yín, ṣugbọn èmi yóo tilẹ̀ tún dì kún un ni. Ẹgba ni ó fi nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.”

15. Nítorí náà, ọba kò gbọ́ ti àwọn eniyan náà, nítorí pé OLUWA alára ni ó fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí rí bẹ́ẹ̀, kí ọ̀rọ̀ OLUWA lè ṣẹ, tí ó bá Jeroboamu ọmọ Nebati sọ, láti ẹnu wolii Ahija ará Ṣilo.

16. Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé, ọba kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dá a lóhùn pé,“Kí ló kàn wá pẹlu ìdílé Dafidi?Kí ló dà wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese?Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ pada sílé yín,kí Dafidi máa bojútó ilé rẹ̀!”

17. Gbogbo Israẹli bá pada sílé wọn; ṣugbọn Rehoboamu ń jọba lórí àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Juda.

18. Lẹ́yìn náà, Rehoboamu ọba rán Adoniramu, tí ó jẹ́ ọ̀gá àgbà àwọn tí wọn ń kó àwọn eniyan ṣiṣẹ́ tipátipá, láti lọ bá àwọn ọmọ Israẹli, wọ́n sì sọ ọ́ ní òkúta pa. Rehoboamu bá múra kíá, ó bọ́ sinu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀, ó sá lọ sí Jerusalẹmu.

19. Láti ìgbà náà ni Israẹli ti ń bá ìdílé Dafidi ṣọ̀tẹ̀ títí di òní yìí.

20. Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ pé Jeroboamu ti pada dé láti ilẹ̀ Ijipti, wọ́n pè é sí ibi ìpàdé kan tí wọ́n ṣe, wọ́n sì fi jọba Israẹli. Kò sí ẹni tí ó tẹ̀lé ìdílé Dafidi, àfi ẹ̀yà Juda nìkan ṣoṣo.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 12