Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 12:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Rehoboamu lọ sí Ṣekemu, nítorí pé gbogbo Israẹli ti péjọ níbẹ̀ láti fi jọba.

2. Nígbà tí Jeroboamu ọmọ Nebati gbọ́ ìròyìn yìí ní Ijipti, (níbẹ̀ ni ó ń gbé láti ìgbà tí ó ti sá lọ fún Solomoni ọba), ó pada wá sílé láti Ijipti.

3. Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ pè é, òun ati gbogbo wọ́n sì tọ Rehoboamu lọ, wọ́n wí fún un pé,

4. “Àjàgà wúwo ni Solomoni baba rẹ gbé bọ̀ wá lọ́rùn. Ṣugbọn bí o bá dín iṣẹ́ líle baba rẹ yìí kù, tí o sì mú kí ìgbé ayé rọ̀ wá lọ́rùn, a óo máa sìn ọ́.”

5. Rehoboamu bá dá wọn lóhùn pé, “Ẹ máa lọ ná, lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, ẹ pada wá gbọ́ èsì.” Àwọn eniyan náà bá pada lọ.

6. Rehoboamu ọba bá lọ jíròrò pẹlu àwọn àgbààgbà tí wọ́n jẹ́ olùdámọ̀ràn Solomoni baba rẹ̀ nígbà ayé rẹ̀, ó bi wọ́n léèrè pé, “Irú ìdáhùn wo ni ó yẹ kí n fún àwọn eniyan wọnyi?”

7. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o bá ṣe bí iranṣẹ fún àwọn eniyan wọnyi lónìí, tí o sì sìn wọ́n, tí o sì fún wọn ní èsì rere sí ìbéèrè tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ, ìwọ ni wọn óo máa sìn títí lae.”

8. Ṣugbọn ó kọ ìmọ̀ràn tí àwọn àgbààgbà fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jíròrò pẹlu àwọn ọdọmọkunrin, ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí wọ́n jọ dàgbà pọ̀, tí wọ́n wà ní ààfin pẹlu rẹ̀.

9. Ó bi wọ́n léèrè, ó ní, “Kí ni ìmọ̀ràn tí ẹ lè gbà mí, lórí irú ìdáhùn tí a le fún àwọn eniyan tí wọ́n ní kí n dín ẹrù wúwo tí baba mi dì lé àwọn lórí kù?”

10. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ohun tí o óo wí fún àwọn tí wọ́n ní baba rẹ di ẹrù wúwo lé àwọn lórí, ṣugbọn kí o bá àwọn dín ẹrù yìí kù ni pé ìka ọwọ́ rẹ tí ó kéré jùlọ tóbi ju ẹ̀gbẹ́ baba rẹ lọ.

11. Sọ fún wọn pé, ‘Ṣé ẹ sọ pé ẹrù wúwo ni baba mi dì rù yín? Tèmi tí n óo dì rù yín yóo tilẹ̀ tún wúwo jù bẹ́ẹ̀ lọ; ati pé ẹgba ni baba mi fi ń nà yín, ṣugbọn àkeekèé ni n óo máa fi ta yín.’ ”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 12