Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 11:24-31 BIBELI MIMỌ (BM)

24. Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun Hadadeseri ọba, tí ó sì ti pa àwọn ará Siria tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, Resoni di olórí àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan tí wọ́n kó ara wọn jọ, tí wọn ń gbé Damasku. Àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá fi jọba ní Damasku.

25. Ọ̀tá gidi ni ó jẹ́ fún Israẹli ní ìgbà ayé Solomoni, ó sì ṣe jamba bí Hadadi ti ṣe. Ó kórìíra àwọn ọmọ Israẹli, òun sì ni ọba ilẹ̀ Siria.

26. Ẹnìkan tí ó tún kẹ̀yìn sí Solomoni ni ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ń jẹ́ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ará Sereda, ninu ẹ̀yà Efuraimu, obinrin opó kan tí ń jẹ́ Serua ni ìyá rẹ̀.

27. Ìdí tí ó fi kẹ̀yìn sí Solomoni nìyí:Nígbà tí Solomoni fi ń kún ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu, tí ó sì ń tún odi ìlú náà kọ́,

28. ó ṣe akiyesi Jeroboamu pé ó jẹ́ ọdọmọkunrin tí ó ní akitiyan. Nígbà tí Solomoni rí i bí ó ti ń ṣiṣẹ́ kára kára, ó fi ṣe olórí àwọn tí wọn ń kóni ṣiṣẹ́ tipátipá ní gbogbo agbègbè ẹ̀yà Manase ati Efuraimu.

29. Ní ọjọ́ kan, Jeroboamu ń ti Jerusalẹmu lọ sí ìrìn àjò kan, wolii Ahija, láti Ṣilo sì pàdé òun nìkan lójú ọ̀nà, ninu pápá.

30. Wolii Ahija bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè tuntun tí ó wọ̀, ó ya á sí ọ̀nà mejila.

31. Ó fún Jeroboamu ni mẹ́wàá ninu rẹ̀, ó ní, “Gba mẹ́wàá yìí sọ́wọ́, nítorí OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí n wí fún ọ pé, òun óo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Solomoni òun óo sì fi ẹ̀yà mẹ́wàá fún ọ.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 11