Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 11:20-29 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Arabinrin ayaba Tapenesi yìí bí ọmọkunrin kan fún Adadi, ó sọ orúkọ rẹ̀ ní Genubati. Inú ilé Farao ọba ni ayaba Tapenesi ti tọ́ ọmọ náà dàgbà, láàrin àwọn ọmọ ọba.

21. Nígbà tí Adadi gbọ́ ní Ijipti pé Dafidi ọba ti kú, ati pé Joabu, balogun rẹ̀ náà ti kú, ó wí fún Farao pé, “Jẹ́ kí n pada lọ sí ìlú mi.”

22. Farao bá bi í léèrè pé, “Kí lo fẹ́ tí o kò rí lọ́dọ̀ mi, tí o fi fẹ́ máa lọ sí ìlú rẹ?”Ṣugbọn Adadi dá a lóhùn pé, “Ṣá jẹ́ kí n máa lọ.”

23. Ọlọrun tún mú kí Resoni ọmọ Eliada dojú ọ̀tá kọ Solomoni, sísá ni Resoni yìí sá kúrò lọ́dọ̀ Hadadeseri, ọba Soba, tí ó jẹ́ ọ̀gá rẹ̀.

24. Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun Hadadeseri ọba, tí ó sì ti pa àwọn ará Siria tí wọ́n wà lẹ́yìn rẹ̀, Resoni di olórí àwọn ìgárá ọlọ́ṣà kan tí wọ́n kó ara wọn jọ, tí wọn ń gbé Damasku. Àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bá fi jọba ní Damasku.

25. Ọ̀tá gidi ni ó jẹ́ fún Israẹli ní ìgbà ayé Solomoni, ó sì ṣe jamba bí Hadadi ti ṣe. Ó kórìíra àwọn ọmọ Israẹli, òun sì ni ọba ilẹ̀ Siria.

26. Ẹnìkan tí ó tún kẹ̀yìn sí Solomoni ni ọ̀kan ninu àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ tí ń jẹ́ Jeroboamu, ọmọ Nebati, ará Sereda, ninu ẹ̀yà Efuraimu, obinrin opó kan tí ń jẹ́ Serua ni ìyá rẹ̀.

27. Ìdí tí ó fi kẹ̀yìn sí Solomoni nìyí:Nígbà tí Solomoni fi ń kún ilẹ̀ tí ó wà ní apá ìlà oòrùn Jerusalẹmu, tí ó sì ń tún odi ìlú náà kọ́,

28. ó ṣe akiyesi Jeroboamu pé ó jẹ́ ọdọmọkunrin tí ó ní akitiyan. Nígbà tí Solomoni rí i bí ó ti ń ṣiṣẹ́ kára kára, ó fi ṣe olórí àwọn tí wọn ń kóni ṣiṣẹ́ tipátipá ní gbogbo agbègbè ẹ̀yà Manase ati Efuraimu.

29. Ní ọjọ́ kan, Jeroboamu ń ti Jerusalẹmu lọ sí ìrìn àjò kan, wolii Ahija, láti Ṣilo sì pàdé òun nìkan lójú ọ̀nà, ninu pápá.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 11