Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 11:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọpọlọpọ àwọn obinrin àjèjì ni Solomoni fẹ́, lẹ́yìn ọmọ Farao, ọba Ijipti, tí ó kọ́kọ́ fẹ́, ó tún fẹ́ ará Moabu ati ará Amoni, ará Edomu ati ará Sidoni, ati ará Hiti.

2. Solomoni ọba fẹ́ wọn bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli tẹ́lẹ̀, pé wọn kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè náà, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọdọ̀ fi ọmọ fún wọn; kí àwọn orílẹ̀-èdè náà má baà mú kí ọkàn àwọn ọmọ Israẹli ṣí sọ́dọ̀ àwọn oriṣa wọn.

3. Ẹẹdẹgbẹrin (700) ni àwọn obinrin ati ọmọ ọba tí Solomoni gbé níyàwó, ó sì tún ní ọọdunrun (300) obinrin mìíràn. Àwọn obinrin náà sì mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun.

4. Nígbà tí Solomoni di àgbàlagbà, àwọn iyawo rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ ṣí kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, ó ń bọ àwọn oriṣa àjèjì, kò sì ṣe olóòótọ́ sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ mọ́, bíi Dafidi, baba rẹ̀.

5. Ó bẹ̀rẹ̀ sí bọ Aṣitoreti, oriṣa àwọn ará Sidoni ati oriṣa Milikomu, ohun ìríra tí àwọn ará Amoni ń bọ.

6. Ohun tí Solomoni ṣe burú lójú OLUWA, kò sì jẹ́ olóòótọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ̀.

7. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ kan sí orí òkè ní ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu fún oriṣa Kemoṣi, ohun ìríra tí àwọn ará Moabu ń bọ, ati fún oriṣa Moleki, ohun ìríra tí àwọn ará Amoni ń bọ.

8. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fún gbogbo àwọn iyawo àjèjì tí ó fẹ́, tí wọn ń sun turari, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn oriṣa wọn.

9. Inú bí OLUWA sí Solomoni, nítorí pé, ọkàn rẹ̀ ti yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó fara hàn án nígbà meji,

10. tí ó sì pàṣẹ fún un nítorí ọ̀rọ̀ yìí pé kò gbọdọ̀ bọ oriṣa. Ṣugbọn kò pa òfin OLUWA mọ́.

11. OLUWA bá sọ fún Solomoni pé, “Nítorí pé o ti ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ, o kò pa majẹmu mi mọ́, o kò sì tẹ̀lé ìlànà tí mo pa láṣẹ fún ọ, dájúdájú n óo gba ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, n óo sì fi fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 11