Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 10:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba gbọ́ òkìkí ọgbọ́n Solomoni, ó wá sí Jerusalẹmu láti fi àwọn ìbéèrè tí ó takókó dán an wò.

2. Ó kó ọpọlọpọ iranṣẹ lẹ́yìn, ó sì di turari olóòórùn dídùn, pẹlu òkúta olówó iyebíye ati ọpọlọpọ wúrà ru ọpọlọpọ ràkúnmí; ó wá sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sọ gbogbo ohun tí ó wà lọ́kàn rẹ̀ patapata fún un.

3. Solomoni dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè rẹ̀, kò sì sí ohunkohun tí ó le fún Solomoni láti ṣàlàyé.

4. Nígbà tí ọbabinrin Ṣeba rí i bí Solomoni ti gbọ́n tó, ati irú ààfin tí ó kọ́,

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 10