Sadoku alufaa ati Natani wolii sì ti fi àmì òróró yàn án ní ọba ní odò Gihoni. Lẹ́yìn náà, wọ́n ti pada lọ sí ààrin ìlú, wọ́n sì ń hó fún ayọ̀. Ariwo sì ti gba gbogbo ìlú. Ìdí rẹ̀ ni ẹ fi ń gbọ́ ariwo.