Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 1:37-53 BIBELI MIMỌ (BM)

37. Bí OLUWA ti wà pẹlu kabiyesi, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ó wà pẹlu Solomoni, kí ó sì mú kí ìgbà tirẹ̀ tún dára ju ìgbà ti kabiyesi, oluwa mi, Dafidi ọba lọ.”

38. Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya, pẹlu àwọn ará Kereti ati àwọn ará Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, bá gbé Solomoni gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Dafidi ọba, wọ́n sì mú un lọ sí odò Gihoni.

39. Sadoku alufaa, bá mú ìwo tí wọ́n rọ òróró olifi sí, tí ó ti mú láti inú àgọ́ OLUWA jáde, ó sì ta òróró náà sí Solomoni lórí. Wọ́n fọn fèrè, gbogbo wọn sì hó pé, “Kí Solomoni, ọba, kí ó pẹ́.”

40. Gbogbo eniyan bá tẹ̀lé e pada, wọ́n ń fọn fèrè, wọ́n ń hó fún ayọ̀. Ariwo tí wọn ń pa pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì tìtì.

41. Bí Adonija ati gbogbo àwọn tí ó pè sí ibi àsè rẹ̀ ti ń parí àsè, wọ́n gbọ́ ariwo náà. Nígbà tí Joabu gbọ́ fèrè, ó bèèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ gbogbo ariwo tí wọn ń pa ninu ìlú yìí?”

42. Kí ó tó dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufaa, dé. Adonija sọ fún un pé, “Máa wọlé bọ̀; eniyan rere ni ìwọ, ó sì níláti jẹ́ pé ìròyìn rere ni ò ń mú bọ̀.”

43. Jonatani bá dáhùn pé, “Rárá o, kabiyesi ti fi Solomoni jọba!

44. Ó sì ti rán Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba pé kí wọ́n tẹ̀lé Solomoni, wọ́n sì ti gbé e gun orí ìbaaka ọba.

45. Sadoku alufaa ati Natani wolii sì ti fi àmì òróró yàn án ní ọba ní odò Gihoni. Lẹ́yìn náà, wọ́n ti pada lọ sí ààrin ìlú, wọ́n sì ń hó fún ayọ̀. Ariwo sì ti gba gbogbo ìlú. Ìdí rẹ̀ ni ẹ fi ń gbọ́ ariwo.

46. Solomoni ti gúnwà lórí ìtẹ́ ọba.

47. Kí ló tún kù! Gbogbo àwọn iranṣẹ ọba ni wọ́n ti lọ kí Dafidi ọba, pé, ‘Kí Ọlọrun rẹ mú kí Solomoni lókìkí jù ọ́ lọ, kí ìjọba rẹ̀ sì ju tìrẹ lọ.’ Ọba bá tẹríba, ó sì sin Ọlọrun lórí ibùsùn rẹ̀,

48. ó ní ‘Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí ó jẹ́ kí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ mi jọba lónìí, tí ó sì jẹ́ kí n fi ojú mi rí i.’ ”

49. Ẹ̀rù ba gbogbo àwọn tí wọ́n lọ bá Adonija jẹ àsè, gbogbo wọ́n bá dìde, olukuluku bá tirẹ̀ lọ.

50. Ẹ̀rù Solomoni ba Adonija tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi sá lọ sinu Àgọ́ OLUWA, tí ó sì di ìwo pẹpẹ mú.

51. Wọ́n sọ fún Solomoni ọba pé ẹ̀rù rẹ ń ba Adonija ati pé ó wà níbi tí ó ti di ìwo pẹpẹ mú, tí ó sì wí pé, àfi kí Solomoni ọba fi ìbúra ṣèlérí pé kò ní pa òun.

52. Solomoni dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ olóòótọ́, ẹnikẹ́ni kò ní fi ọwọ́ kan ẹyọ kan ninu irun orí rẹ̀, ṣugbọn bí ó bá hùwà ọ̀tẹ̀, yóo kú.”

53. Solomoni ọba bá ranṣẹ lọ mú Adonija wá láti ibi pẹpẹ. Adonija lọ siwaju ọba, ó sì wólẹ̀. Ọba sọ fún un pé kí ó máa lọ sí ilé rẹ̀.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 1