Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Kinni 1:34-45 BIBELI MIMỌ (BM)

34. kí Sadoku, alufaa ati Natani wolii, fi àmì òróró yàn án ní ọba níbẹ̀, lórí gbogbo Israẹli. Lẹ́yìn náà, kí ẹ fọn fèrè, kí ẹ sì hó pé, ‘Kí ẹ̀mí Solomoni, ọba, kí ó gùn!’

35. Lẹ́yìn náà, ẹ óo tẹ̀lé e pada wá síhìn-ín kí ó wá jókòó lórí ìtẹ́ mi; nítorí pé òun ni yóo jọba lẹ́yìn mi. Òun ni mo yàn láti jọba Israẹli ati Juda.”

36. Bẹnaya bá dáhùn pé, “Àṣẹ! Kí OLUWA Ọlọrun rẹ bá wa lọ́wọ́ sí i.

37. Bí OLUWA ti wà pẹlu kabiyesi, bẹ́ẹ̀ náà ni kí ó wà pẹlu Solomoni, kí ó sì mú kí ìgbà tirẹ̀ tún dára ju ìgbà ti kabiyesi, oluwa mi, Dafidi ọba lọ.”

38. Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya, pẹlu àwọn ará Kereti ati àwọn ará Peleti tí wọn ń ṣọ́ ọba, bá gbé Solomoni gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Dafidi ọba, wọ́n sì mú un lọ sí odò Gihoni.

39. Sadoku alufaa, bá mú ìwo tí wọ́n rọ òróró olifi sí, tí ó ti mú láti inú àgọ́ OLUWA jáde, ó sì ta òróró náà sí Solomoni lórí. Wọ́n fọn fèrè, gbogbo wọn sì hó pé, “Kí Solomoni, ọba, kí ó pẹ́.”

40. Gbogbo eniyan bá tẹ̀lé e pada, wọ́n ń fọn fèrè, wọ́n ń hó fún ayọ̀. Ariwo tí wọn ń pa pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì tìtì.

41. Bí Adonija ati gbogbo àwọn tí ó pè sí ibi àsè rẹ̀ ti ń parí àsè, wọ́n gbọ́ ariwo náà. Nígbà tí Joabu gbọ́ fèrè, ó bèèrè pé, “Kí ni ìtumọ̀ gbogbo ariwo tí wọn ń pa ninu ìlú yìí?”

42. Kí ó tó dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ, Jonatani, ọmọ Abiatari, alufaa, dé. Adonija sọ fún un pé, “Máa wọlé bọ̀; eniyan rere ni ìwọ, ó sì níláti jẹ́ pé ìròyìn rere ni ò ń mú bọ̀.”

43. Jonatani bá dáhùn pé, “Rárá o, kabiyesi ti fi Solomoni jọba!

44. Ó sì ti rán Sadoku alufaa, ati Natani wolii, ati Bẹnaya ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba pé kí wọ́n tẹ̀lé Solomoni, wọ́n sì ti gbé e gun orí ìbaaka ọba.

45. Sadoku alufaa ati Natani wolii sì ti fi àmì òróró yàn án ní ọba ní odò Gihoni. Lẹ́yìn náà, wọ́n ti pada lọ sí ààrin ìlú, wọ́n sì ń hó fún ayọ̀. Ariwo sì ti gba gbogbo ìlú. Ìdí rẹ̀ ni ẹ fi ń gbọ́ ariwo.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Kinni 1