Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 9:33-37 BIBELI MIMỌ (BM)

33. Jehu bá ké sí wọn, ó ni, “Ẹ Jù ú sílẹ̀.” Wọ́n bá ju Jesebẹli sí ìsàlẹ̀, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ta sí ara ògiri ati sí ara àwọn ẹṣin, àwọn ẹṣin Jehu sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ kọjá.

34. Lẹ́yìn náà, ó wọlé, ó jẹ, ó mu, lẹ́yìn náà, ó ní, “Ẹ lọ sin òkú obinrin ẹni ègún yìí nítorí pé ọmọ ọba ni.”

35. Àwọn ọkunrin tí wọ́n lọ sin òkú náà kò rí nǹkankan àfi agbárí, ati egungun ọwọ́ ati ti ẹsẹ̀ rẹ̀.

36. Nígbà tí wọ́n pada wá sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún Jehu, ó ní, “OLUWA ti sọ tẹ́lẹ̀ láti ẹnu wolii Elija, iranṣẹ rẹ̀ pé, ajá ni yóo jẹ òkú Jesebẹli ní agbègbè Jesireeli.

37. Òkú rẹ̀ yóo fọ́n ká bí ìgbẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò ní lè dá a mọ̀ mọ́.”

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 9