Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àwọn Ọba Keji 9:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Eliṣa pe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii, ó sọ fún un pé, “Ṣe kánkán, kí o lọ sí Ramoti Gileadi pẹlu ìgò òróró yìí.

2. Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, bèèrè Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi; mú un wọ yàrá kan lọ kúrò láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.

3. Kí o da òróró inú ìgò yìí sí i lórí, kí o sì wí pé, OLUWA sọ pé, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ Kí o sì yára sá kúrò níbẹ̀.”

4. Ọdọmọkunrin wolii náà bá lọ sí Ramoti Gileadi.

5. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bá àwọn olórí ogun níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ó wí pé, “Balogun, wọ́n rán mi níṣẹ́ sí ọ.”Jehu bá bèèrè pé, “Ta ni ninu wa?”Ọdọmọkunrin náà bá dáhùn pé, “Ìwọ ni, Balogun.”

6. Àwọn mejeeji bá jọ wọ inú yàrá lọ, ọdọmọkunrin wolii náà da òróró sí orí Jehu, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, àwọn eniyan OLUWA.’

7. O óo pa ìdílé oluwa rẹ, Ahabu ọba rẹ́, kí n lè gbẹ̀san lára Jesebẹli fún àwọn wolii mi ati àwọn iranṣẹ mi tí ó pa.

Ka pipe ipin Àwọn Ọba Keji 9